Nigeria Air force: Awakọ̀ Ọ̀gágun Alex Badeh tí wọ́n pa kò kú

Alex Badeh

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Àkọlé àwòrán,

Ilé isẹ́ ọmọogun òfúrufú lórílẹ̀èdè Naijiria ti kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Naijiria láti sọ́ra fún ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀.

Ile isẹ ọmọogun ofurufu ti ni awakọ Ọgagun Alex Badeh ko ku, lẹyin ti awọn agbẹgbọn kan pa ọgaagun naa ni ilu Abuja.

Agbẹnusọ fun ile isẹ iroyin awọn ọmọogun ofurufu lorilẹede Naijiria, Air Commodore Ibikunle Daramola ninu atẹjade to fi lede ni alaafia ni awakọ ọgagun naa wa nibi ti o ti n gba iwosan ni ile iwosan awon ọmọ ogun ofurufu.

Daramọla ni awọn ti n tọ ipase awọn to sekupa Ọgagun Alex Badeh naa ni asiko to n bọ lati oko rẹ ni ọna Abuja si Kebbi ni asalẹ Ọjọ Isẹgun.

Ile isẹ ọmọogun naa wa kilọ fun awọn ara ilu lati sọra fun iroyin ẹlẹjẹ, pẹlu ikilọ pe iroyin ti ki n se otitọ le dina iwadii ti awọn n se lọwọ lati fi awọn to sekupa Ọgagun naa jofin.