Police- Ahesọ ọ̀rọ̀ lásan ní Dino Melaye ń sọ

Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, @dinoofficial

Àkọlé àwòrán,

Ọgá àgbà ọlọ́pàá ń lépa ẹmi mi -Dino Melaye

Àṣojú ẹkùn Iwọ̀-òòrùn Kogi ni ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, Sẹnatọ̀ Dino Melaye ti fẹ̀sùn kan ọ̀gá àgbà àjọ ọlọ́pàá, Ibrahim Idris.

O ni pé Ibrahim ń gbìyànjú láti mú òun kí wọn le gún oun ni abẹ́rẹ́ ikú ni.

Sẹnatọ náà ní IGP ti pasẹ fún àwọn ti ó ran láti se iṣẹ́ náà.

Dino Melaye fí ẹsùn kan ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Ibrahim Idris lóri atẹjíṣẹ́ twitter

Àkọlé fídíò,

Èpo ọwọn, sunkere-fakere ọkọ àti àwọn olósà jẹ́ ipenija lójú pópó

Àkọlé fídíò,

Oludije ipò Gómìnà labẹ asia PDP ní Oyo sọrọ nípa Ladoja

Sùgbọ́n, agbẹnusọ àjọ ọlọ́pàá, Jimoh Moshood ti sàpèjúwe ọ̀rọ̀ Melaye gẹ́gẹ́ bí àhesọ ọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ awàdà àti ọ̀rọ̀ tó lé ṣi àwọn ará ìlú lọ́nà.

Ó ní kò sí ètò kankan láti ọ̀dọ̀ àjọ ọlọ́pàá láti mú Dino Melaye, sùgbọn tó ba jẹ́ pé ó ní ọ̀nà tó ti gbà ṣẹ̀ sófin kó jáde wá níbi tó farapamọ sí láti wá jẹ́wọ́

" A fẹ́ lo àsìkò láti sọ fún gbogbo àwọn èèkàn ìlú bí sẹnátọ pé òfin dè wọn láti ma sọ ọ̀rọ̀ to lè si ará ìlú lọ́nà tábi tó lé dá èdèìyèdè sílẹ̀ láàrín ìlú".

Àkọlé fídíò,

Asisat Oshoala: ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá nínú eré bọ́ọ̀lù

Àkọlé fídíò,

The seed: Àwa sì wá láti mú ẹ̀bùn fún Ọba tí a bí lónìí