Baba Go-Slow: Mí ò le rẹ̀wẹ̀sì nítorí orúkọ yìí

Ààrẹ mUHAMMADU bUHARI

Oríṣun àwòrán, Bayo Omoboriowo

Àkọlé àwòrán,

Baba Go-Slow: Mí ò le rẹ̀wẹ̀sì nítorí orúkọ yìí

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti ni gbogbo orúkọ Baba Go-Slow ti wọn ń pe oun ní ìgboro kò tú irun kan lára oun oo, sùgbọ́n bí oun yóò ṣe maa ṣe Go-Slow nìyí títí ti òun yoo fi gba gbogbo owo ìlú ti àwọn aléjẹ fẹ́nu lọ́lẹ̀ tí kójẹ bó ti wù kó pẹ́ tó.

Ààrẹ fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ nílùú Abuja nígbà ti àwọn kan láti olúùlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wá sàbẹ̀wò síi láti kii kú ọdun kérésìmesì nílé ìjọba.

Ní pàtàkì jùlọ ààrẹ Buhari ni ìdí ti òun ṣe fẹ lọ gẹ́gẹ́ bi ààrẹ lẹ́ẹ̀kan síi lọ́dún 2019 ní pé ìdojúkọ òun kò ti kúro nínú àwọn àlàsílẹ̀ nínú ìpolngo ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress lọ́dún 2015.

Ó sàlàyé pé àwọn pàtàkì tí ìpolongo dúró lé lóri ní gbígbogun ti ìwà àjẹbánu, ètò ààbo àtí mímú ìdàgbàsókè bá ètò ọ̀rọ̀ ajé.

Àkọlé fídíò,

The seed: Àwa sì wá láti mú ẹ̀bùn fún Ọba tí a bí lónìí

Àkọlé fídíò,

Asisat Oshoala: ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá nínú eré bọ́ọ̀lù