Calabar Carnival 2018 kún fún oríṣiríṣi àṣà àti ìṣe

Oṣù Kejìlá ọdọọdún ni ayẹyẹ Calabar Carnival ma n wáyé ní ìpínlẹ̀ Cross Rivers fún ìgbélárugẹ́ àṣà.

Olúkòso arẹ̀kújayé pidán lójú gbogbo ènìyàn
Àkọlé àwòrán,

Olúkòso arẹ̀kújayé pidán lójú gbogbo ènìyàn

Àkọlé àwòrán,

Ọmọ Yorùbá ń tàdí réke gẹ́gẹ́ bí onílù ṣe ń kán'lù sí i níbàdí

Àkọlé àwòrán,

Àwọ̀ àsìá orílẹ̀èdè Nàìjíríà ni àwọn kan tilẹ̀ fi ṣe ara wọn l'ọ́ṣọ̀ ọ́

Àkọlé àwòrán,

Àtèèyàn àteégún ló pitú ijó

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ọmọge awẹ́lẹ́wà gan an kò gbẹ́yìn pẹ̀lú àwọn nkan tí wọ́n fi ṣara l'óge

Àkọlé àwòrán,

Níṣe ni ìlù Bàtá n ró pọnlá-pọnlá látọwọ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ káàrọ̀ ò jíire

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ti ẹ̀yà Igbo nàá wá s'ágbo àríyá

Àkọlé àwòrán,

Gbogbo nkan tó wáyé ní Calabar Carnival 2018 fihàn pé Nàìjíríà kún fún àwọn àṣà tó gbayì

Àkọlé àwòrán,

Àṣà tí a kò bá fihan ọmọ, yóò parun. Àwọn ọ̀dọ́langba nàá kò gbẹ́yìn níbi ayẹyẹ nàá

Àkọlé àwòrán,

Ijó Yorùbá gbayì púpọ̀ níbikíbi ó sì máa ń wu ni lórí jọjọ

Àkọlé àwòrán,

Aṣọ àti àwọn ìlẹ̀kẹ̀ tó j'ojú ní gbèsè n pe ara wọn rán níṣẹ́ ní Calabar Carnival 2018

Àkọlé àwòrán,

Àjó làágùn l'áwọn olùkópa jó níbi ayẹyẹ Calabar Carnival 2018

Àkọlé àwòrán,

Ó jọ bíi kóle kóle ṣùgbọ́n ìgbádùn láwọn ijó bá dé ni Calabar Carnival 2018