2018: Badeh, Alkali bẹ̀rẹ̀ ọdún 2018 ṣùgbọ́n wọn kò là á já

Awọn eeyan n gbe oku awọn ti awọn darandaran fulani kan pa nipinlẹ Benue

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ẹ̀mí làwọn apànìyàn rán lọ s'ọ́run àpàpàǹdodo lọ́dún 2018

Ọpọ ipaniyan lo waye lọdun 2018 lorilẹede Naijiria.

Eyi ko si fẹrẹ yẹ lori ipenija ọrọ abo to mẹhẹ lorilẹ-ede Naijiria eleyi to ti mu akiyesi awọn orilẹ-ede agbaye lati tan imọlẹ wọn si bi nnkan ṣe nlọ lorilẹede Naijiria paapaa julọ lori ọrọ abo.

Tolori tẹlẹmu lawọn to lugbadi ipaniyan yi ti ọpọ ile alayọ si bọ sinu ibanujẹ.

Àkọlé fídíò,

Tsunami: Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan ti Jumasil ti sọnù ni wọ́n rii padà

Diẹ lara awọn ipaniyan to milẹ bi ọwara ojo lorilẹ-ede Naijiria lọdun 2018 niwọnyii:

Ọgagun agba, Alex Badeh, Ọgagun agba ileeṣẹ ọmọogun apapọ Naijiria tẹlẹ

Oríṣun àwòrán, NAF

Àkọlé àwòrán,

Ìpèníjà ọ̀rọ̀ àbò lórílẹ̀èdè Nàìjíríà fa ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ariwo lọọ́dún 2018

Alex Badeh ni Ọgagun agba ileeṣẹ ọmọogun apapọ Naijiria labẹ iṣejọba aarẹ ana, Goodluck Jonathan lẹyin to ti jẹ ọgagun agba ileeṣẹ ọmọogun ofurufu lorilẹede Naijiria laaarin oṣu kẹwa, ọdun 2012 si ọdun 2014.Link

Ni oṣu keji, ọdun 2016 ni ajọ EFCC fi ẹsun kan an pe o ṣe ẹgbẹlẹgbẹ owo ilu ti o to N3.9 biliọnu baṣubaṣu lasiko ti o fi jẹ ọgagun agba ileeṣẹ ọmọogun ofurufu.

Bakan naa ni wọn fi ẹsun kan awọn ọmọ ati iyawo rẹ pẹlu.

Ni ọjọ kejidinlogun oṣu kejila ni awọn agbebọn kan yinbọn pa Ọgagun agba Alex Badeh ni opopona marosẹ Keffi si Abuja.

Ọgagun Idris Alkali, adari eto iṣakoso nileeṣẹ ọmọogun oriilẹ lorilẹede Naijiria

Oríṣun àwòrán, Nigeria Army

Àkọlé àwòrán,

Ninu kọnga kan ni wọn ti ri oku ọgagun Idris Alkali

Ọgagun Idris Alkali ni adari eto iṣakoso nileeṣẹ ọmọogun oriilẹ lorilẹede Naijiria ki o to fẹyinti ni ọdun 2018.

Ni ọjọ kẹta, oṣu kẹsan ni wọn kede pe wọn n wa ọgagun naa lẹyin ti o poora lasiko ti o fi n rinrinajo lati Abuja lọ si ipinlẹ Bauchi.

Ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹsan kan naa ni wọn ri ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla ti o wa rinrinajo naa ninu adagun odo kan lagbegbe Dura-Du.

Ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ ni awọn ọdọ ti wọn n fẹhonu han kan ni wọn pa a nitori lọjọ ti wọn ṣe iwọde wọn naa ni ọgagun Alkali gunle irinajo aremabọ rẹ naa.

Ninu kọnga kan ni wọn ti ri oku ọgagun agba naa ki wọn to gbe oku rẹ jade ti wọn si lọ sin in.

Hauwa Mohammed, oṣiṣẹ ajọ aṣeranwọ Red cross

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oṣiṣẹ agbẹbi ni Hauwa Mohammed pẹlu ọkan ninu awọn ileewosan ajọ aṣeranwọ alagbelebu pupa, Red cross, ICRC ti wọn n ṣiṣẹ iranwọ lawọn agbegbe ti wahala ti n waye ni ẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria.

Oṣu kẹta ọdun 2018 ni awsn agbebọn Boko Haram ji gbe pẹlu awọn oṣiṣẹ ajọ alagbelebu pupa, Red Cross ni ileewosan naa to wani ilu Rann ni agbegbe Maiduguri nipinlẹ Borno.

Ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn ni Hauwa nigba ti wọn jii gbe.

Awọn agbebọn Boko Haram pa Hauwa lẹyin ti gbedeke oṣu mẹsan ti wọn fun ijọba lati duna dura pẹlu wọn lori itusilẹ rẹ kọja laisi igbesẹ kankan latọdọ ijọba apapọ.

Àkọlé fídíò,

Asisat Oshoala: ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá nínú eré bọ́ọ̀lù

Àkọlé fídíò,

Saba Gul: Ọmọbìnrin aláìlápa tí o fẹ̀ dì agbẹjọro

Saifura Hussaini Khorsa. Oṣiṣẹ ajọ UNICEF

Awọn agbebọn Boko Haram ji Saifura Hussaini Ahmed Khorsa, ọmọ ọdun marundinlọgbọn gbe wọn si paa ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹsan ọdun 2018.

Àkọlé fídíò,

Tsunami: Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan ti Jumasil ti sọnù ni wọ́n rii padà

Oṣu kẹta ọdun 2018 ni wọn jii gbe lasiko to fi n ba ajọ idagbasoke awọn ọmọde labẹajọ iṣọkan agbaye, UNICEF, ṣiṣẹ ni ilu Rann, lẹkun ila oorun ariwa orilẹ-ede Naijiria.