Awọn ìmúra tó dá orí ayélujára rú jùlọ lọ́dún 2018

ìmúra lọdún 2018

Oríṣun àwòrán, FATHIABALOGUN, Tiannahsplacempire

Àkọlé àwòrán,

ìmúra lọdún 2018

Aṣọ Super Eagles

Ìgbà layé, ìgbà lásọ, ìgbà ní gbogbo ǹkan., ojú rèé ìran rèé lọ́dún 2018.

Oriṣiríṣii nkan lo ṣelẹ lágbo oṣere, láàrin àwọn olórin, àwọn arìnrín oge àti agbo eré bọọlu ni Naijiria lọdun 2018 bí àwọn ènìyàn ṣe wọ àwọn aṣọ àwòdami ẹnu.

Oríṣun àwòrán, Super Eagles

Àkọlé àwòrán,

Ọjọ ti àwọn onisowo to ń ta asọ super Eagle bẹ̀rẹ̀ títà. Bi àwọn ènìyàn ṣe to láti ra asọ náà

Aṣọ tó kọ́kọ́ dàlú rú lọdún 2018 ní jẹsí (jersey) ikọ̀ super Eagles ti wọn polongo títà rẹ̀ lọ́jọ́ kini, osù Kẹ́fà ọdún 2018.

Ìyàlẹnu ló jẹ bí oníruuru àwọn ènìyàn ṣe ya sí ilé iṣẹ́ NIKE láti lọ ràá, tó si tan laáàrin iṣẹ́ju mẹ́tà ti wọn bẹ̀rẹ̀ si ni tà.

Oríṣun àwòrán, Super Eagles

Àkọlé àwòrán,

Awọn oyinbo o gbéyin nínú àwọn to ra aṣọ náà

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó aṣọ náà lé ní ọgbọ̀n ẹgbẹ̀rún lé ọgọ́fà náírà, síbẹ̀ àwọn enìyàn bo asọ náà wìtìwìtì.

Oríṣun àwòrán, Super eagles

Àkọlé àwòrán,

Awọn olorin ò gbẹ́yìn nínú ríra aṣọ Super Eagles ti a n wi yìí

Ibi Ami ẹyẹ AMVCA

A tún ṣe alábapàdé awọn imura tó yani lẹ̀nú lásíkò amì ẹ̀yẹ fún àwọn oṣèré jákèjádo Afíríkà. Ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ wọn ló péjú síbẹ̀, bí wọn ṣe wá péjú yìí bẹẹni àwọn aṣọ aláranbara náà ṣe ń jẹyọ.

Oríṣun àwòrán, Iamnino_b

Àkọlé àwòrán,

Gbaajúgbaja oṣèré Ninalowo Bolanle náà ò gbẹyìn nínu àwọn okúnrin ti ìmúra wọn fakọyọ lọdún 2018

Èyí o wa jojú ní gbèsè bí Bolanle Ninalowo, oṣèrè fíìmù Yoruba àti lédè Òyìnbo ṣe dúró déédé l'ọ́mọkùnrin níbi àmì ẹ̀yẹ náà.

Oríṣun àwòrán, Fathiabalogun

Àkọlé àwòrán,

Ọ̀kan lára àwọn oṣèrè kan náà tún rèé, tó wọ aṣọ ti àwọn ènìyàn ń wári fún lọdun 2018

Oríṣun àwòrán, @bammybestowed

Àkọlé àwòrán,

Ẹnu kò sìn lára Bambam tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdíjé Big Brother Naija l'ọ́dún 2018 nítorí aṣọ aláràmbarà tó wọ́

Ifilọlẹ̀ aṣọ Star Boy

Gbajúgbajà olórin tàkasúfe, Wizkid lásìkò tó fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Nike lati ṣe aṣọ jersey jáde. Aṣọ ọ̀hún ní àmi àwọ ewé àti funfun, èyí tó fi àwọ àsíá orílẹ̀èdè Nàìjírìá hàn.

Síṣe àgbékalẹ̀ aṣọ náà jẹ́ àtòpọ ẹbun ọpọlọ ti ọlọrun fun unàtí ànfààní tó rigbà lọwọ àwọn alábasiṣẹpọ̀ rẹ̀.

Asọ yìí bákan náà gbòde kan láti inú osù kẹsan ọdún 2018.

Oríṣun àwòrán, Wizkid official

Àkọlé àwòrán,

Gbajugbaja olorin takasufe ni Wizkid, to si ti ṣe àwọn ori to mìlú titi jáde

Oríṣun àwòrán, Wizkidofficial

Àkọlé àwòrán,

Awọn ìmúra tó dá orí ayélujára rú jùlọ lọ́dún 2018

EfCC I'M HERE

Òkan gbòógì ní yìí bakan náà lásìkò ti àjọ EFCC pé gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe láti wa wi ti ẹnu rẹ̀ to ba ti kúrò nípò gẹ́gẹ́ bii gómìnà.

Lásìkò ti yóò lọ síbẹ̀, àkọlé aṣọ to wọ lọ ni EFCC I'M HERE, tó túmọ̀ sí EFCC mo dé.

Níṣe ni àwọn ènìyàn tún gba èyí bí ẹni gba igbá ọtí.

Oríṣun àwòrán, Fayoseofficial

Àkọlé àwòrán,

Gomina ana ní ìpínlẹ̀ Ekiti Ayodele Fayose lásìkò tó ń sàbẹ̀wo si àjọ EFCC

Ayẹyẹ àyájọ ìmúra oge nípinlẹ̀ Eko (#lagosfashionshow)

Hmmm, lọdun 2018 ni ìpìnlẹ̀ Eko ṣe ayẹyẹ ètò ìmúra oge tó mìlú tiìtì. Yorùbá bọ wọn ni oríṣiríṣi ọ̀bẹ làári lọ́jọ́ ikú erín.

Díẹ̀ lára àwọn àṣọ to dá ẹrọ ayélujara rú rèé níbi ayẹyẹ náà.

Àkọlé àwòrán,

Ọ̀kan nínú àwọn to péju nibi ayẹyẹ náà rèé

Àkọlé àwòrán,

Obinrin kan rèé nínú àwọn to lọ si ibi ayẹyẹ Lagos Fashion show

Àkọlé àwòrán,

Awọn ìmúra tó dá orí ayélujára rú jùlọ lọ́dún 2018

Àkọlé àwòrán,

Awọn ìmúra tó dá orí ayélujára rú jùlọ lọ́dún 2018

Ẹwẹ̀, kò tán síbẹ̀ oo, atún ri àwọn aṣọ míràn ti kò níṣe pẹ̀lú ayẹyẹ kankan sùgbọ́n tó jẹ́ àwòdami ẹnu.

Ṣé ti ẹni to fi gúrúrú ṣe ọ̀ṣọ́ sí ara aṣọ ni tàbí èyí to lo ẹ̀pà láti ràn aṣọ tírẹ̀

Àkọlé àwòrán,

Imúra tó lààmìlaka lọdún 2018 ni aṣọ ẹlẹ́pà yìí.

Oríṣun àwòrán, Tiannahsplacempire

Àkọlé àwòrán,

Ọkan tún rèé ẹ gbà yí yẹ̀wò

Àkọlé àwòrán,

Tiwa Savage lásìkò tó ń gba àmi ẹyẹ MTV

Àkọlé àwòrán,

Guguru ní wọn fi ṣe aṣọ yìí, o rẹwa púpọ̀