2019: Ààrẹ Buhari ní òun yóò rẹ́yìn Boko Haram bópẹ́-bóyá

ipolongo Buhari

Aarẹ orilẹede Naijiria, ti ṣeleri ati ropin gulegule awọn agbebọn Boko Haram.

Aarẹ ṣeleri yii nibi iṣide ipolongo rẹ fun idibo aarẹ ọdun 2019 to waye nilu Uyo, ipinlẹ Akwa Ibom.

Aarẹ Buhari ni ko si ani-ani pe ijọba ibilẹ mẹtadinlogun ni awọn agbebọn Boko Haram n ṣakoso rẹ ni ipinlẹ Borno ati Yobe ni igba ti oun fi de ipo aarẹ lọdun 2015, eleyi ti o ni ko ri bẹẹ mọ bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"A oo le wọn kuro lorilẹede yii patapata,"

Aarẹ fi kun un pe ohun mẹta-eto abo, ọrọ aje ati gbigbogun ti iwa ijẹkujẹ- ti iṣejọba oun ṣeleri lasiko ipolongo fun idibo ṣaaju ibo apapọ 2015, ni o ti mu ṣẹ.

Oríṣun àwòrán, Nigeria presidency

Àkọlé àwòrán,

APC kede Muhammadu Buhari gẹgẹ bii alaga igbimọ ipolongo idibo yan aarẹ wọn lowurọ ọjọ ẹti ki ipolongo to bẹrẹ

Bakan naa lo ni awọn ọmọ orilẹede Naijiria ko ni kabamọ ti wọn ba lee tun dibo fun oun gẹgẹ bi aarẹ lẹẹkan sii.

Aarẹ Buhari n bẹrẹ ipolongo pẹlu bi ọwọja awọn agbebọn Boko Haram tun ṣe dabi eyi to tun n gbopọn sii bayii.

Oríṣun àwòrán, Nigeria presidency

Àkọlé àwòrán,

Ileeṣẹ ọmọogun Naijiria ni awọn ibudo ọmọogun meji lawọn agbebọn BokoHaram ti jagun gba

Ikọlu awọn agbebọn naa ti di lemọlemọ lẹnu lọwọlọwọ yii eleyi ti o si n gbẹmi ọgọrọ ọmọogun ọlọpaa ati araalu.

Nibayii awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ lorilẹede Naijiria ni awọn ibudo ọmọogun meji to wa lẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria ni awọn agbebọn BokoHaram ti jagun gba bayii.

Oríṣun àwòrán, Nigeria presidency

Àkọlé àwòrán,

Ikọlu awọn agbebọn Boko Haram ti di lemọlemọ lẹnu lọwọlọwọ yii

Ninu atẹjade kan, wọn ni, ikọlu ilu Baga to wa nitosi adagun odo lake Chad waye ni ọjọ keji ọjọ keresimesi

Bi o tilẹ jẹ pe awọn ologun ni awọn ṣi n ba awọn agbebọn naa waako lagbegbe naa, ọpọ to ba BBC sọrọ ṣalaye pe awọn agbebọn Boko Haram ti gba iṣakoso olu ileeṣẹ ikọ ọmọogun alajumọni, Multinational Joint Task Force ti wọn gbe kalẹ nibẹ lati koju awọn agbebọn naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: