Saba Gul: Ọmọbìnrin aláìlápa tí o fẹ̀ dì agbẹjọro

Saba Gul: Ọmọbìnrin aláìlápa tí o fẹ̀ dì agbẹjọro

Bi ẹṣin ba dani a tun gun ni.

Ipinu Saba Gul ree eleyi ti o sọ di orin apilẹkọ to fi n gbe igbesi aye rẹ.

Ọsọrọ olomọge yi ko ni apa mejeeji ṣugbọn ipenija yi ko jẹ idiwo fun lati ma gbe igbe aye rẹ.

Okun Ina manamana ni o gbamu nigba ti o wa ni ọmọ ọdun maarun eleyi ti mo ki awọn dokita ge apa rẹ mejeeji lati doola ẹmi rẹ.

Lati igba naa ni o ti bẹrẹ si ni lo ẹsẹ rẹ fii ṣe ohun to yẹ ki o fi apa ṣe.

''Awọn kan a ma sọ wi pe iṣowolofo ni kin wn ran mi lọ ile iwe ṣugbọn mi o ka ọrọ wọn kun''

Saba Gul lero lati di agbẹjọro lọjọ iwaju ki o ba le ma ja fun ẹtọ awọn obinrin ati awọn eeyan miran to ba ni ipenija kan tabi omiran.

''Mo fẹ rin kaakiri,kin mọ ilu ati awọn aṣa miran to yatọ si tiwa.O wu mi lati mu ayipada rere ba awujọ wa lorileede Pakistan''