Awọn ọmọ Naijiria n sọ ọrọ oriṣii nípa ọrọ Buhari ati Shagari

shagari Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ko si ẹni ti kò lè ṣẹ ara wọn laye, aforijin lo dara julọ

Iku alumuntu looṣa to n kọ ẹbọ nigba ti asiko ba tó.

Bala Shagari, ọkan lara awọn ọmọ Alhaji Shehu Shagari to tukọ orilẹ-ede Naijiria titi di 1983 sọ fawọn oniroyin pe baba oun padà forijin Buhari ko to dẹni ilẹ̀.

Bala to jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn ọdọ NYCN ni

Image copyright @shehu
Àkọlé àwòrán Shagari Dariji awon bii Ojukwu, Yakubu Gowon ati Micheal okpara nigba iṣejọba rẹ

Lọjọ Aiku ni Bala sọ ọrọ yii nigba ti aarẹ Buhari n ṣabẹwọ ẹ pẹlẹ si ẹbi oloogbe. Bakan naa lo fidunnu ẹbi han pe aarẹ Buhari wa yẹ oloogbe naa si.

Bakan naa lo ṣalaye pe baba oun kò fi iwe akọsilẹ ogún pinpin silẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAfro Brazilians: ìlú Rio ni a máa kọ ilé ìṣẹmbáyé náà sí

Awọn eniyan ni wọn ti n sọ oriṣiiriṣii ọrọ nipa aforiji Shagari paapaa fun aarẹ Buhari. Loju awọn kan, Buhari lo fopin airotẹlẹ si iṣejọba alagbada.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Shagari pada dariji Buhari ko to kú

Ohun to kọju si ẹnikan, ẹyin lo kọ si ẹlomii bi ilu gangan, awọn miran gba pe igbesẹ to dara ni Buhari gbe nipa diditẹ gbajọba ni 1983

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAlapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?

Awọn miran gba pé oju meji ni Buhari fi idajọ iditẹ gbajọba rẹ ṣe laarin oloogbe Ekwueme ati Shehu Shagari.

Sugbọn ẹni to mu omele lọwọ lo mọ ohun ti oun n fi omele sọ, Buhari ni àyàn to n lu ilu yii pe ki Olorun tẹ oloogbe si afẹfẹ rere ati pe oun ti ṣe abewo si ẹbi rẹ bi o ṣe yẹ.

Buhari paṣẹ pe ki Naijiria sọ asia kalẹ fọjọ mẹta nitori Shagari

Ẹni ti ọla ba tọ si ni a n bú ọla fún ni ọrọ iku aarẹ Shehu Shagari to ti wọ káà ilẹ̀ sùn bayii.

Aarẹ Mohammadu Buhari kẹdun iku oloogbe naa, o kede pe ki gbogbo asia Naijiria wa ni idaji fun ọjọ meta lati fi bu ọla fun Shagari.

Bi o ṣe kede sisọ asia kalẹ si idaji naa ni awọn ọmọ Naijria ti n fi ero wọn han lori ayelujara.

Loju awọn kan bii Chijoke, o n beere irufẹ ọla ati ọna ibanikẹdun wo ni Buhari n ṣe lẹyin to jẹ pe oun lo gba ijọba lọwọ Shagari pe:

Image copyright @Shagariofficial
Àkọlé àwòrán Okú Sheu Shagari ti wọn káà ill sùn ní ìlú Shagari Sokoto

Loju àwọn ọmọ Naijiria mii, ni ṣe lo yẹ ki Buhari kọkọ tọrọ aforijin lọwọ Shagari ati Ekwueme to fagidi gba ijọba lọwọ wọn ni 1984.

Loju awọn mii, iku to n pa ojugba ẹni, owe nla lo n pa fun ni. Ki onikaluku maa palẹmọ di iru ọjọ bayii ti ina a dilẹ̀ leyin asunṣujẹ.

Bẹẹ, aare Buhari gba pe ẹni rere lo lọ nitori pe Shehu Shagari ṣeniyan pupọ ni ọrọ ti ọpọlọpọ ti n fapajanu le lori

Image copyright @Shagariofficial
Àkọlé àwòrán Okú Sheu Shagari ti wọn káà ill sùn ní ìlú Shagari Sokoto

Ariṣe ni arika, arika ni baba iregun, awọn ọmọ Naijiria n sọrọ lori iṣẹ ti Shagari ṣe nigba to wa lori oye pe:

Wọn ti sin oku aarẹ Shehu Shagari ni Sokoto

Okú ààrẹ Nàìjíríà nígbà kàn rí, Alhaji Sheu Shagari tó jẹ́ Ọlọ́run nípè lálẹ́ ọjọ Ẹti tí wọ káà ilẹ̀ sùn ni ààgo mẹ́ta àbọ̀ ọ̀sán ọjọ Abamẹta nílé rẹ̀ tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Sheu Shagari ní ìpínlẹ̀ Sokoto.

Wọn gbé wọ ilẹ̀ ní dédé ààgo mẹta àbọ gééregé tí ọjọgbọ́n Shehu Galadachi tó jẹ olóri fasikti Usma-DanFodio ní Sokoto sáájú àdúrà.

Ẹní ọmọ ọdún Mẹ́tàdínláàdọ́run ní ààrẹ Shagari wọ ilú Abuja lọjọ́ Iṣegun lẹ́yìn ti ilera rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní mẹ́hẹ, sùgbọn to jẹ́ Ọlọ́run nípè lálẹ́ ọ́jọ́ Jimoh

Gomina Aminu Tambuwal ló gba òkú ààrẹ nígbàkan rí ní pápákọ̀ òfurufú Sultan Abubakar láti gbe lọ ilú rẹ̀ Shagari níbi tó ti wọ káà ilẹ̀ sùn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÈpo ọwọn, sunkere-fakere ọkọ àti àwọn olósà jẹ́ ipenija lójú pópó
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAsisat Oshoala: ìbẹ̀rẹ̀ mi kò rọrùn rárá nínú eré bọ́ọ̀lù
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSaba Gul: Ọmọbìnrin aláìlápa tí o fẹ̀ dì agbẹjọro