Afro Brazilians: ìlú Rio ni a máa kọ ilé ìṣẹmbáyé náà sí

Afro Brazilians: ìlú Rio ni a máa kọ ilé ìṣẹmbáyé náà sí

Àwọn ọmọ Yorùbá ilẹ̀ Brazil ṣetán láti kẹ́kọ̀ọ́ síi nípa orírun wọn nílẹ̀ Oodua.

BBC Yorùbá ba àwọn ọmọ ilẹ Brazil ti wọn wa orisun wọn wa si Naijiria sọrọ.

Wọn mẹnuba awọn oriṣa Yoruba ti awọn naa n sìn bii Sango, Ogun, Ọbatala àti bẹẹ bẹẹ lọ

Arole Oodua ti fidunnu rẹ han si igbesẹ awọn iran Yoruba ni Brazil yii.

Oọni ṣelẹri lati ran wọn lọwọ sii ki wọn lè tubọ mọ̀ nipa orirun wọn nilẹ Oodua.

Ọọni gba pe wọn a fun wọn ni diẹ lara awọn ère Yoruba ki wọn lo fi pilẹ ile iṣẹmbaye ti wọn pinnu lati kọ si Rio, ni Brazil.

Bakan naa ni Ọjaja keji ṣeleri lati ran awọn akọṣẹmọṣẹ lọ ba wọn ṣiṣẹ ti asiko ba to ki idagbasoke le ba ẹkọ wọn nipa orisun wọn sii.