New Year Message 2019: Buhari gba àwọn ọmọ Nàìjíríà níyànjú lórí àlááfíà lọ́dún 2019

aarẹ Buhari Image copyright Nigeria Presidency
Àkọlé àwòrán Ààrẹ Buhari ní kò sí ìdí fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti fòyà nítorí ìdìbò 2019

Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe pipada si ipo ohun fun saa keji kii ṣe tiku tiye o.

Aarẹ Buhari ni ohun to jẹ oun logun naa ni eto idibo alaafia ti ko ni wahala ninu ti araye si lee fi ọwọ rẹ sọya.

Ninu ọrọ ikini ku ọdun to fi ranṣẹ sawọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ni aarẹ Buhari ti sọ ọrọ yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIkorodu Bois: Ko si ẹni ti a kò lè sín jẹ!

"Ko yẹ ki eto idibo di tipa tikuuku, bẹẹni ko yẹ ki a maa sunmọ idibo labẹ iṣejọba tiwantiwa pẹlu ifoya."

Aarẹ ni lọwọ yii pupọ awọn oludije fun ipo aarẹ ninu idibo apapọ ọdun 2019 ni wọn ti tọwọ bọ iwe adehun alaafia, eyi to ni o fi da oun loju pe alaafia yoo jọba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAlapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?

Aarẹ ni oun mọ pe alaafia, abo to peye ati igbayegbadun laraalu n fẹ, ti o si ni ki awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria o maa foya nitori alaafia yoo jọba lasiko idibo ọdun 2019.

Buhari ni orilẹ-ede Naijiria yoo kuro ni ipele ireti bọ si imuṣẹ ileri eleyi to si ni o yẹ ko jẹ ojuuṣe gbogbo mutumuwa lorilẹede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌwà ipá nínú ìdílé máa ń bí ìgè àti àdùbí ni tó lè já sí ikú