2019 Elections:Yuguda, Mu'azu fi PDP sílẹ̀ lọ APC ní Bauchi

Gomina Bauchi nigba kan ri Adamu Muazu ati Isa Yuguda Image copyright Adamu Muazu and Isa Yuguda

Àwọn èèkàn ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Bauchi ti fi ẹgbẹ naa silẹ lọ si APC nigba ti Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣe abẹwo si ipinlẹ naa ni Ọjọ Abamẹta.

Lara awọn ti aarẹ gba wọ ẹgbẹ rẹ ni gomina ipinlẹ naa meji nigba kan ri Adamu Mu'azu ati Isa Yuguda. Eyi to ya ni lẹnu ju ni ti Mu'azu to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nigba kan ri.

Awọn to tun ba wọn kọwọ rin lọ APC ni igbakeji gomina ipinlẹ naa nigba kan ri Abdulmalik Mahmud ati ọkan lara awọn oloye ẹgbẹ oṣelu PDP kan, Babayo Gamawa.

Image copyright Bashit Ahmad/Twitter

Iroyin ni ọgọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lo fi ẹgbẹ naa silẹ lọ APC. Fifi ẹgbẹ kan silẹ lọ omiran wọpọ laaarin awọn oloṣelu ninu ipolongo ibo ni Naijiria.

Ninu ọrọ ni Bauchi, Buhari ki awọn to ṣẹṣẹ wọ ẹgbẹ oṣelu rẹ naa kaabọ, to si rọ wọn ki wọn ṣiṣẹ takuntakun fun aṣeyọri APC ninu ibo gbogbogbo to nbọ.

O tun gbe oṣuba fun ijọba ara rẹ pe awọn ti ṣe daadaa lori ọrọ aabo, ọrọ aje ati gbigbe ogun ti iwa jẹgudujẹra.

Nibi ipolongo naa, alaga ẹgbẹ oṣelu APC Adams Oshiomhole fi ẹsun kan oludije fun ipo aarẹ labẹ PDP, Atiku Abubakar pe ti o ba wọle, oun ati PDP yoo ta ile iṣẹ epo rọbi Naijria, NNPC.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption2019 election: Àwọn olùdíje fún ipò gómìnà nípínlẹ̀ Kwara sọ̀rọ̀ lórí ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe