Buhari: Òpùrọ́ àti òjòwú ni Olusegun Obasanjo

Buhari Obasanjo Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ìjọba fèsì lẹ́yìn tí Ọbasanjo fi léde wí pé ìjọba Buhari kò yàtọ̀ sí tí Abacha pẹ̀lú ìmọ̀ràn pé kó lọ sinmi.

Ẹro awọn ọmọ Naijiria se ọtọọtọ lori lẹta ti Baba Ọbasanjo ko si Aarẹ Muhammadu Buhari lori isejọba rẹ ọdun mẹrin ati eto idibo osu to n bọ.

Ọpọlọpọ awọn to fesi si ọrọ to n lọ naa lori ẹrọ ayelujare ni wọn bu ẹnu atẹ lu lẹta Baba Ọbasanjo, ti awọn miran si wa lẹyin Baba Ọbasanjo.

Bakan naa ni awọn miran ni Ọbasanjọ jẹ eniyan ti o máa n sọ wi pe, ade gun loni, ti a tun sọ wi pe ade ko gun mọ lọla.

Awọn miran tun dupẹ lọwọ Baba Olusegun Obasanjo pe otitọ ọrọ lo sọ lasiko ti Naijiria nilo ọrọ naa lasiko yii.

Awọn ẹlomiran ni o yẹ ki ijọba apapọ ko fesi si si awọn ẹsun ti Baba Obasanjo fi kan an, kii se ki wọn ma a bu ẹnu atẹ lu ọrọ rẹ.

'Bàbá Ọbasanjo ń jowú Ààrẹ Buhari ni'

Ijọba orilẹ-ede Naijiria ti fun Aarẹ tẹlẹri, Olusegun Obasanjo lesi lẹyin to bu ẹnu atẹ lu isejọba Aarẹ Buhari.

Oluranlọwọ pataki fun Aarẹ Buhari lori ọrọ to jọmọ iroyin, Garba Shehu ti ni irọ patapata ni ọrọ pe ijọba Buhari yoo yi esi idibo gbogboogbo osu to n bọ.

Shehu ni ojowu, opurọ ati odalẹ ni Aarẹ tẹlẹri naa, ati wi pe oun jọwu Aarẹ Buhari ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAtiku ní òun kò dènà kí ọ̀dọ́ kankan dupò ààrẹ ní Nàìjíríà

O fikun wi pe awọn mọ wi pe awọn yoo bori ninu idibo to n bọ, eyi ti yoo si ya awọn ẹgẹ alatako ti Baba Ọbasanjo n satilẹyin fun.

Ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari wa fi kun wi pe ki awọn ọmọ Naijiria o fọkanbalẹ nitori idibo naa yoo lọ ni irọwọrọsẹ lai si magomago.