Femi Falana: Ojú Elzakzaky kan ti fọ́ nítorí àìsí ìtójú tó

Elzakzaky ati Zinat Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Agbẹjọ́rọ̀ fún Elzakzaky, Femi Falana ní ọdún 2015 tí wọn ti wà látìmọ́lé ni wọ́n kò tíì ní ìtọ́jú tó péye.

Ile ẹjọ giga ni Kaduna ti pasẹ ki ijọba ipinlẹ Kaduna fun adari ẹgbẹ Shia lorilẹ-ede Naijiria, Ibrahim Elzakzaky ati iyawo rẹ, Zinat ni eto iwosan to peye.

Adajọ Gideon Kurada pasẹ naa lasiko ti wọn gbo ẹsun onigun mẹjọ ti ijọba ipinlẹ Kaduna fi kan awọn mejeeji pe wọn n daabo bo awọn ọdaran ati awọn apaniyan to n gbogun ti ipinlẹ naa.

Lẹ́yìn òkò ọ̀rọ̀, Buhari àti Ọbasanjọ fẹ̀rín pàdé ara wọn l‘Abuja

Agbẹjọro fun Elzakzaky, Femi Falana sọ fun ile ẹjọ pe lati ọjọ kẹrinla, oṣu kejila, ọdun 2015 ti wọn ti wa latimọle ni wọn ko ti ni itọju to peye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionObasanjo: Atiku kìí se Áńgẹ́lì, àmọ́ yóò se dáadáa ní ìlọ́po méjì ju Buhari lọ

Ninu ọrọ rẹ, Falana ni airi itọju to peye lasiko ni Elzakzaky se padanu oju rẹ kan, ati wi pe ọta ibọn si wa lara iyawo rẹ.

Adajọ Kurada wa sun igbẹjọ naa si Ọjọ Karundinlọgbọn, Osu Kẹta ,ọdun 2019.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEzekwesili: Àfojúsùn mi ni láti mú ààbò ẹ̀mí ọmọ Nàíjíríà ní ọ̀kúnkúndùn
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAtiku ní òun kò dènà kí ọ̀dọ́ kankan dupò ààrẹ ní Nàìjíríà