Nigeria 2019: Amẹrika, Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kò ní ààyò olùdíje fún ààrẹ

Ile ijọba Amerika ati aṣia orilẹede naa Image copyright News4c

Awọn aṣoju orilẹ-ede Amẹrika ati Ilẹ Gẹẹsi ni Nigeria ti ni awọn ko ni aayo kankan lara awọn oludije fun ipo aarẹ ninu idibo ọdun 2019 ti yoo waye ni oṣu keji.

Awọn ileeṣẹ orilẹ-ede mejeeji ni Naijiria jijọ gbe atẹjade kan sita ni Ọjọbọ ninu eyi ti wọn ti ni awọn yoo yan ọpọlọpọ awọn onwoye tí yoo lọ kakakiri awọn ibi idibo lọjọ idibo aarẹ.

Awọn aṣoju orilẹ-ede Amẹrika ni eto idibo to lọ wọrọwọ ti ko si mu wahala dani lo jẹ awọn logun. Wọn ni awọn orilẹ-ede oni ijọba awa-arawa ti n woye bi awọn kan ṣe fẹ fa wahala lakoko idibo naa.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionObasanjo: Buhari ní àìlera lẹ́mìí, lára, àti lọ́kàn.

Orilẹ-ede naa ṣe ileri wi pe ẹnikẹni ti o ba dan iru rẹ wo awọn yoo fi ofin de oun ati awọn ẹbi rẹ ti wọn ko si ni le wọ orilẹ-ede Amẹrika nigbakugba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionìpàdé ìtagbangba ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn olùdíje sípò gomina ní ìpínlẹ̀ Eko.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsinbajo: Ikẹnnẹ yẹ kó jẹ́ Mẹ́kà òṣèlú ni

Ninu ọrọ tiwọn, awọn aṣoju Ilẹ Gẹẹsi ni awọn yoo ṣe atilẹyin fun ajọ eleto idibo INEC lati ri pe idibo na lọ ni irọwọ-rọsẹ.

Atẹjade naa sọ pe, "Awọn ounwoye wa yoo foju sita lati ṣọ awọn agbegbe ti o ṣeeṣe ki wahala bẹ silẹ ni akoko idibo naa."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMurphy Elégungun Rọba: Mo fẹ́ di ẹnití egungun rẹ rọ jùlọ ní àgbáyé
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Obìnrin ló ni ilé àti àdúgbò fún ìdí èyí wọ́n lè ṣe ìlú dáadáa'