Sowore: Ìdí tí mi ò fi lè ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Mogbalu

Fela Durotoye, Kingsley Moghalu ati Omoyele Sowore Image copyright Sahara Reporters
Àkọlé àwòrán Mo kọ lati ṣiṣẹ pẹlu Moghalu - Sowore

Oludije fun ipo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu AAC, Ọmọyẹle Ṣoworẹ ba BBC sọrọ lori ìṣẹlẹ to mu Ezekwesili yọwọ ninu idije dupo aarẹ Naijiria.

Ṣoworẹ sọ fun BBC News Yoruba pe ohun to ṣẹlẹ si Oby Ezekwesili ti awọn ẹgbẹ oṣelu rẹ ACPN fi kọ ẹyin sii le ṣẹlẹ si Kingsley Moghalu ati Fela Durotoye to jẹ oludije YPP ati AAN, ṣugbọn ko le ṣẹlẹ si oun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionObasanjo: Atiku kìí se Áńgẹ́lì, àmọ́ yóò se dáadáa ní ìlọ́po méjì ju Buhari lọ

Alaye to ṣe ni pe, awọn oludije wọn yii darapọ mọ awọn ẹgbẹ oṣelu to ti wa nilẹ tẹlẹ ṣugbọn oun da ti oun silẹ ni tuntun ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:]

O ṣalaye wipe, bo tilẹ jẹ pe awọn oludije to ku ti ni awọn le ṣe atilẹyin fun oludije ti aparapọ ẹgbẹ oṣelu ba fa silẹ, oun ko ro pe iru igbesẹ yii maa waye.

Soworẹ ni idi ni wipe, Moghalu ti sọ pe ipinnu aparapọ ẹgbẹ oṣelu ti ko ba sọ oun di oludije, ko le yọri si rere. O ni nitori naa, oun yoo duro laye ara oun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionìpàdé ìtagbangba ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn olùdíje sípò gomina ní ìpínlẹ̀ Eko.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Obìnrin ló ni ilé àti àdúgbò fún ìdí èyí wọ́n lè ṣe ìlú dáadáa'

Oludije naa ni oun ko ni ibẹru pe ti oun ko ba parapọ pẹlu awọn oludije to ku, oun ko ni wọle.

O sọ fun BBC Yoruba pé, yatọ si pe ẹgbẹ oṣelu oun ni okikii laarin ọmọ Naijiria, oun ni oludije kan ṣoṣọ to ti fi ẹsẹ ba ipinlẹ marundinlogoji ninu mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀tọ̀ ni nkan tí wọ́n sọ fún ẹbí rẹ̀, iṣẹ́ aṣẹ́wó ni wọ́n fi n ṣe
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsinbajo: Ikẹnnẹ yẹ kó jẹ́ Mẹ́kà òṣèlú ni