Buhari yọ adájọ́ àgbà Onnoghen, PDP so ìpolongo ìbo rọ̀

Aa Buhari yan Tanko Ibrahim lati dele de adajọ Onnoghen Image copyright AsoRockVilla
Àkọlé àwòrán Aa Buhari yan Tanko Ibrahim lati dele de adajọ Onnoghen

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni awọn ti so ipolongo ibo wọn rọ̀ tori ipinnu Aarẹ Muhammadu Buhari lati jáwe gbélé ẹ lé Adajọ Agba Walter Onnoghen lọwọ.

PDP sọ lori atẹ Twitter rẹ wipe igbesẹ aarẹ bu ẹtẹ lu iwe ofin Naijiria.

Gomina Ipinlẹ Ekiti Ayodele Fayose ni Aarẹ Muhammadu Buhari n ṣe bii Hitler, olori ijọba Nazi ni Germany to fa ogun agbaye keji ninu eyi ti ọgọrọ eniyan lagbaye ti parun.

Ọrọ Fayose jade nigba to sọrọ lori Twitter nipa igbesẹ Buhari lati yọ Adajọ Agba Walter Onnoghen nipo.

Bẹẹ naa ni, amofin agba kan lorilẹede Naijiria Olisa Agbakoba ni aarẹ Buhari ko ni aṣẹ kankan lati yọ Onnoghen.

Nigba to ba ile iṣẹ BBC sọrọ, ọgbẹni Agbakoba oun ko lee gba ohun ti aarẹ Buhari ṣe gbọ.

"Bi o ba jẹ pe lootọ ni, Buhari fẹ da wahala silẹ lori ọrọ ofin niyẹn. Ana alana ni ile ẹjọ ṣi sọ pe ki wọ́n jami lori ẹjọ yii na.

Pe Buhari wa yọ adajọ agba, leyi ti ko si ninu ofin, emi o mọ iru wahala to le fa o," bẹẹ ni Olisa wi.

Bakan naa, o ni abala ofin kan wa to ṣalaye ilana ati yọ adajọ agba eyi to si ye yekeyeke.

Aàrẹ Ilé Igbimọ Aṣofin Agba, Bukola Saraki naa ke pe aarẹ Buhari lati yi igbesẹ rẹ pada lori Onnoghen.

Oby Ezekwesili naa bẹnu atẹ lu ààrẹ, o si rọ ọ ko yi ọrọ rẹ pada.

O ni aye n wo iṣe aarẹ ti ọrọ naa si le fa wahala.

Reno Omokri to jẹ agbẹnuọ fun aarẹ Goodluck Jonathan bu ẹnu atẹ lu Buhari lapa kan, o si tun bu ẹnu atẹ lu Ezekwesili lapa keji.

O ni nitori pe Ezekwesili ko sọrọ nigba ti Buhari kọkọ bẹrẹ si ni gbogun ti awọn adajọ ni.

Ṣaaju, aarẹ Muhammadu Buhari ti paṣẹ lọ gbele ẹ na fun adajọ agba orilẹede Naijiria Walter Samuel Nkanu Onnoghen.

Ori atẹ Twitter rẹ lo ti ṣe ikede naa.

Oludije ẹgbẹ oṣelu PDP fun ipo aarẹ Atiku Abubakar pe fun iṣọkan laarin awọn adajọ ki wọn baa le gbogun ti iwa aarẹ naa.

O sọ pe o jọ bi ẹni pe Buhari fẹ tun orilẹede Naijria ni.

Bakan naa, o fi hande wi pe aarẹ Buhari ti yan ẹlomiran, Ibrahim Tanko Muhammed gẹgẹ bi adele ni ipo adajọ Onnoghen.

Lọsan ọjọ ẹti, aarẹ ti bura wọle fun ọgbẹni Ibrahim Tanko Muhammed gẹgẹ bi adele adajọ agba tuntun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsinbajo: Ikẹnnẹ yẹ kó jẹ́ Mẹ́kà òṣèlú ni
Image copyright AsoRockVilla
Àkọlé àwòrán Ààrẹ Buhari àti Adájọ́ Walter Onnoghen