Yollywood: Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá tó fẹ́ òṣèré ẹgbẹ́ wọn

Rasaq olayiwola ati moji afolayan iyawo re Image copyright Rasaq olayiwola/damola olatunji
Àkọlé àwòrán Ariwo ìgbéyàwó ò'sèré tó bá tú ká ni aráyé máa ń gbọ́

Ọpọ igba lo jẹ pe igbeyawo to foriṣọnpọn laarin awọn oṣere tiata ni araye maa n ri tabi ni iroyin maa n fọnrere rẹ.

Amọṣa, ọpọ igbeyawo laaarin awọn oṣere tiata lo n duro digbi lai yẹ gẹrẹ ṣugbọn ti ọpọ ko mọ.

BBC News Yoruba ṣe awari diẹ lara awọn igbeyawo wọnyii, awọn si niyii:

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Damọla Ọlatunji ati Bukọla Awoyẹmi (Arugba)

Image copyright Damola oltunji
Àkọlé àwòrán Araye kìí gbọ́ ariwo àwọ̀n tó bá dúró fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.

Ọkan pataki ninu awọn oṣere tiata Yoruba ti wọn n ṣe lọkọlaya ni Bukọla Awoyẹmi ti ọpọ eeyan mọ si 'arugba' gẹgẹ bii ipa ti o ko ninu ere ti ogbontagi akọtan ati adari ere, Tunde Kelani gbe jade ni saa kan pẹlu akọle "Arugba".

Oṣere tiata Yoruba, Damọla Ọlatunji ni o fẹ, Eduwa si ti fi ibeji lantilanti ta wọn lọrẹ.

Rasaq Ọlayiwọla (Ojopagogo) ati Moji Afọlayan

Image copyright Rasaq olayiwola
Àkọlé àwòrán Rasaq Ọlayiwọla (Ojopagogo) ati Moji Afọlayan

Rasaq Ọlayiwọla ti ọpọ eeyan mọ si Ojopagogo fẹ Mojirọla Afọlayan ti oun pẹlu jẹ oṣere tiata. Ọmọ gbajugbaja oṣere ni, Adeyẹmi Afọlayan ti ọpọ mọ si Ade love ni Moji.

Ọjọ kẹta oṣu kejila ọdun 2003 ni wọn ṣe igbeyawo wọn, lẹnu iṣẹ tiata ni a gbọ pe awọn mejeeji ti pade o.

Ṣẹgun Ogungbe ati Atinukẹ , Ọmọwunmi Ogungbe

Image copyright Atinuke ogungbe
Àkọlé àwòrán Ṣẹgun Ogungbe ati Ọmọwunmi, Atinukẹ Ogungbe

Bakan naa, Ṣẹgun Ogungbe, gbajumọ oṣere tiata naa pẹlu kun ara awọn oṣere tiata to fẹ oṣere tiata ẹgbẹ wọn lagbo oṣere Tiata Yoruba.

Iyawo meji ni Ọgbẹni Ogungbe ni. Awọn mejeeji yii lo si jẹ oṣere tiata pẹlu.

Atinukẹ Ogungbe ni iyawo rẹ akọkọ oṣere tiata Yoruba ni. Ọmọ meji ni a gbọ pe wọn ti bi fun ara wọn.

Ọmọwunmi ni orukọ iyawo rẹ keji. Oṣere taiata si ni oun naa pẹlu. Eleduwa si ti fi eso ọmọ si aarin wọn.

Afeez Abiọdun (Afeez Ọwọ) ati Mide Martins

Image copyright AFeez abiodun
Àkọlé àwòrán Afeez Abiọdun (Afeez Ọwọ) ati Mide Martins

Ninu awọn lọkọlaya to gbajumọ ju lagbo ere tiata Yoruba kaakiri agbaye ni Afeez Abiọdun ti ọpọ mọ si Afeez Ọwọ ati Mide Martins.

Gbajumọ oṣere, adari ere, olotu ere ati akọtan ni Afeez ọwọ ti iyan Mide Martins pẹlu ko ṣee kọ kere rara.

Rafiu Balogun ati Fausat Balogun (Madam Ṣajẹ)

Image copyright fausat balogun
Àkọlé àwòrán Rafiu Balogun ati Fausat Balogun (Madam Ṣajẹ

Lara awọn agba lọkọlaya lagbo oṣere tiata yoruba ni Fausat Balogun ti ọpọ mọ si 'Madam Ṣajẹ' wa. Ọpọ ni ko si mọ pe laarin agbo tiata ni eekan oṣere tiata yii ti yan aayo tirẹ pẹlu.

Alagba Rafiu Balogun toun pẹlu jẹ oṣere tiata, akọtan ati olotu ere ni ọkọ 'Madam ṣajẹ'

Gẹgẹ bi a ti ṣe gbọ, o ti le ni ọgbọn ọdun ti awọn mejeeji yii ti pade ara ni ikorita irinajo ifẹ.

Image copyright Lanko ọmọba Dubai

Gbogbo awọn onworan ere tiata Yoruba ko lee gbagbe obinrin adẹrinpoṣonu kan to jẹ pe ilana aditi ni awọn gbe ipa idẹrin pẹẹkẹ araalu gba ni tiwọn. Kudirat Shorẹmi ni orukọ rẹ ṣugbọn 'No Network ni ọpọ ololufẹ ere tiata yoruba mọ wọn si.'

Adeọla Shorẹmi ti ọpọ eeyan mọ si 'Princess Lanko ọmọọba Dubai ti oun pẹlu jẹ eekan adẹrinpoṣonu lagbo ere tiata Yoruba ni ọkọ 'No Network'

Iroyin sọ pe kii ṣe inu agbo ere tiata ni awọn mejeeji yii ti pade ṣugbọn ọpọ aimoye awọn araalu ni wọn ti dẹrin pẹẹkẹ wọn.

Ẹniọla Afeez ati Esther Kalẹjaye

Image copyright AFeez eniola
Àkọlé àwòrán Ẹniọla Afeez ati Esther Kalẹjaye

Ẹniọla Afeez ati Esther Kalẹjaye ti ọpọ mọ si Ọmọ jọ ibo pẹlu kun ara awọn oṣere tiata Yoruba ti wọn n ṣe lọkọlaya.

Gbajumọ olotu, oṣere ati akọtan ere tiata ni Ẹniọla Afeez, Esther, iyawo rẹ naa kopa ni ọpọlọpọ awọn ere, paapaa julọ, ninu ere Jenifa.

Lukman Raji ati Bukky Adekongbe (Aminatu papapa)

Image copyright Bukky raji
Àkọlé àwòrán Lukman Raji ati Bukky Adekongbe (Aminatu papapa)

Njẹ ẹ mọ Ọkọ Aminatu papapa

Lukman Raji ati Bukky Adekongbe ti ọpọlọpọ mọ si Aminatu papapa pẹlu naa n ṣe lọkọlaya lagbo ere tiata Yoruba.

Iroyin to n tẹwa lọwọ si tun fi idi rẹ mulẹ pe bi a ṣe n sọrọ yii, Eduwa ti fi ọmọ ta wọn lọrẹ.

Sunday Ọmọbọlanle (Aluwẹ) ati Peju Ọmọbọlanle (Peju Ogunmọla)

Image copyright Peju omobolanle
Àkọlé àwòrán Sunday Ọmọbọlanle (Aluwẹ) ati Peju Ọmọbọlanle (Peju Ogunmọla)

Sunday Ọmọbọlanle ati Peju Ogunmọla naa ti pẹ ninu irinajo ifẹ lagbo ere tiata Yoruba.

Adẹrinpoṣonu ti ko lafiwe ni Sunday Ọmọbọlanle ti ọpọ eeyan mọ si 'Aluwẹ' tabi 'Papi luwẹ'. Laarin agbo ere tiata ni oun ati iyawo rẹ, Peju, to jẹ ọkan lara awọn ọmọ agba oṣere to ti fi ilẹ bora, Oloye Ogunmọla.

Ọmọ wọn, Sunkanmi, pẹlu ti n goke agba lẹnu iṣẹ tiata pẹlu.

Related Topics