Nigeria 2019 Elections: Ẹnikẹ́ni tó bá ṣáájú láti jì àpótí ìbò ẹ̀mí rẹ̀ ló fi ń ṣeré- Buhari

Aworan Aarẹ Buhari

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Buhari ko fi ẹlẹ fi ikilọ rẹ ranṣẹ si awọn to n gbero lati da ibo ru

Aarẹ Muhammadu Buhari ti fi ikilọ sita f'awọn to ba n gbero lati da ibo Aarẹ to n bọ lọna ru.

O ni ''ẹnikẹni to ba ro wi pe ohun lee ko awọn janduku sẹyin lati ji apoti ibo tabi da ibo ru n fi ẹmi ara rẹ ṣere ni.''

Nibi ipade idankọkọ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC to n waye nilu Abuja laarẹ Buhari ti tutọ soke foju gba a lọjọ Aje.

Àkọlé fídíò,

Janduku yinbọn nilu Iwara

Àkọlé fídíò,

Àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà fohùn ránṣẹ́ sí ìjọ̀ba tí yóò wọlé

Aarẹ Buhari ti o n dije fun ipo Aarẹ lẹẹkan sii labẹ asia ẹgbẹ naa ni oun ti paṣẹ fun awọn oṣiṣẹ aabo lorileede Naijiria lati toju bọ gbogbo ibi ti awọn ọdanran ba wa ṣaaju idibo naa.

''A ko ni tori wi pe a n dije ninu ibo ki a wa fi aabo ara ilu ṣere''

Nibi ipade naa la tun ti ri awọn eekan ẹgbẹ bi igbakeji Aarẹ Yemi Osinbajo ati alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Adams Oshiomọlẹ to peju sibẹ.

Ẹwẹ, aarẹ Buhari tun mẹnu ba isunsiwaju ibo aarẹ fun ọsẹ kan eleyi ti ajọ eleto idibo Naijiria kede.

O ni o ku diẹ kaato bi Inec ti ṣe sun ibo naa siwaju o si ni o di dandan ki awọn wadi ọfintoto lẹyin ibo idi ti Inec ṣe sun ibo naa siwaju.

''Kani awọn ile asofin ni ko buwọlu owo ti wọn fẹ fi ṣeto idibo ni, a o mọ wi pe idi pataki niyẹn ṣugbọn ki wọn kan sun idibo siwaju lai nidi to gba ọgbọn, eyi ku diẹ kaato''.