PDP:Buhari ni kẹ dalẹ́bi tí wahala ìdìbò bá bẹ́ sílẹ̀

Aare Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/@OfficialPDPNig/Getty

Àkọlé àwòrán,

Buhari

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party PDP ti figbe sita pe ijọba to wa lori oye ati ẹgbẹ oṣelu APC n gbero lati doju eto ijọba arawa bole ki wọn si da wahala silẹ lorileede Naijiria.

Wọn fi ọrọ yi sita gẹgẹ bi idahun si ihalẹ ti aarẹ Buhari ṣe nibi ipade bonkẹlẹ ẹgbẹ APC to waye l'Abuja lọjọ Aje.

Nibi ipade naa, Aarẹ Buhari ni ''ẹnikẹni to ba ro wi pe ohun lee ko awọn janduku sẹyin lati ji apoti ibo tabi da ibo ru n fi ẹmi ara rẹ ṣere ni.''

Lọjọ Aje kanna ni ẹgbẹ PDP ṣe ipade pajawiri lasiko igba ti ipade APC naa n waye.

Kola Olongbodiyan to jẹ agbodegba ẹgbẹ naa lẹyin ipade wọn ni awọn lero wi pe ihalẹ Aarẹ Buhari ki ṣe wi pe o fẹ fi ṣe boju boju ki awọn ọmọogun baa le yinbọn lu awọn eeyan ki wọn si jin apoti ibo gbe.

Olongbodiyan ni ki aarẹ Buhari lọ mọ wi pe ''ko si iru ihalẹ to le ha mọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn ko fi ni tu jade lati wa dibo yọ kuro loye lọjọ kẹtalelogun Oṣu keji.''

Oríṣun àwòrán, Kola Ologbondiyan/Facebook

O sọ pe awọn ti gbo iroyin pe ijọba Buhari ti paṣẹ fun Inec lati ṣe atunto aaye ti wọn gbe awọn ọga eleto idibo nipinlẹ kọọkan si ki wọn ba le ṣe wuruwuru lasiko ibo.

O ni iru ọgbọn bayi ni wọn da ti wọn fi satunto awọn ọga ọlọpaa nipinlẹ saaju idibo

Kini APC sọ?

Lẹyin ipade pajawiri ti wọn ṣe lọjọ Aje, ẹgbẹ oṣelu APC fi abajade ipade ti wọn naa sita lorukọ alaga ẹgbẹ Adams Oshiomole.

Ninu atẹjade naa wọn rọ awọn oṣiṣẹ alaabo lati fi ijiya to tọ jẹ awọn to ba kopa ninu iwa janduku tabi jiji apoti ibo gbe..

Lori ọrọ orukọ awọn oludari eto idibo lawọn ijọba ibilẹ ati ipinlẹ ti Inec fi sita, APC ni pupọ ninu wọn ni wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ PDP ti wọn si parọwa si Inec lati gbe igbese atunṣe rẹ.

Ko daju wi pe APC ri atẹjade PDP nitori atẹjade ti wọn ko mẹnu ba ohun ti wọn sọ nipa Aarẹ Buhari ati erongba rẹ lati fi ọmọ ogun ṣe bojuboju lati dunkoko mọ oludibo.