Amosun ṣọ̀fọ̀ Adesanya ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ rẹ̀ l'Abẹokuta

adesanay ati Adeoluwa
Àkọlé àwòrán,

Ọfọ nla ṣe nipinlẹ Ogun lọna Kọbapẹ

Akọwe àgba fún ipinlẹ Ogun, Taiwo Adeoluwa àti Ogbeni Adesanya ti gbogbo eniyan mọ si 'ọrẹ gomina' ni ijamba ọkọ loju ọna Kọbapẹ nitosi Abẹokuta nipinlẹ Ogun.

Ogbeni Clement Oladele to jẹ ọga agba ileeṣẹ ẹ̀ṣọ́ ààbò ojú pópó ti fìdí ẹ múlẹ̀ pé Adesanya, ọ̀rẹ́ gomina Amosun ti jáde láyé nígbà tí Adeoluwa, akọ̀wé ìpínlẹ̀ Ogun wà nílé ìwòsàn.

O ni wọn ti gbe òkú ọrẹ gomina lọ sile igbokupamọsi nigba ti Adeoluwa n gba itọju to peye nile iwosan ijọba ti Federal Medical Center nilu Abẹokuta nipinlẹ Ogun.

Àkọlé fídíò,

Scrabble: Yorúbà Scrabble ni àkọ́kọ́ ní èdè abínibí nílẹ̀ Afrika

Wọn ni Taiwo Adeoluwa fori gba ni ni eyi ti wọn n tọju lọwọ ni ìdí àbá.

Ijamba ọkọ naa ṣẹlẹ ni opopona Shagamu si Abẹokuta nínú eyi ti ẹ̀mí ọrẹ gomina ba a lọ ṣaaju idibo aarẹ to n lọwọ kaakiri Naijiria bayii.

Awọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ojú pópó ni ijamba naa ṣẹlẹ nitosi ile iwe Day Water Man College ni Kobapẹ.

Ogbeni Clement ni oun ba Taiwo Adeoluwa sọrọ ni eyi to fidi ẹ mulẹ pe o ti n gba itọju to yẹ

Àkọlé fídíò,

#NigeriaDecides: BBC ti wa ni gbogbo ìpínlẹ̀ Naijiria láti firoyin gbogbo tóo yin létí