2019 Election: Oniṣẹ́ ibi làwọn to ni kí Atiku ma lọ si ile ẹjọ lóri èsì ìdìbò ààrẹ-Obasanjo

Obasanjo ati Atiku
Àkọlé àwòrán 2019 Election: Bí Buhari ba le lọ Kóòtù ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta- Obasanjo

Ààrẹ àná ní orílẹ̀-èdè Naìjíríà Olusegun Obasanjo ti gbéna woju gbogbo àwọn to ń parọwa sí Atiku Abubakar ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP to fidirẹmi ninu ìdìbò ààrẹ to wáyé losu tó kọja pé kí ó màa gbé ọ̀rọ̀ náà lọ si ilé ẹjọ.

Aàrẹ Muhammadu Buhari ti ẹgbẹ́ oṣèlú APC fi ẹyìn Atiku Abubakar janlẹ̀ nínú ìdìbò tó wáye lajọ́ kẹtàlélogun osu Keji ti ó si pinu láti ṣejọ lóri abajáde èsì ìdíbò ọhun láti gba ẹtọ òun pada.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOshisko twins: Ojú wa rí, ṣùgbọ́nÌgbọ́raẹniyé ló ń ràn wá lọ́wọ́

Ọ̀pọ̀ àwọn olóṣelu àti ọ̀tọ̀kùlú ló ti ba sọ̀rọ̀ láti fija fọ́lọ́run jà sùgbọ́n ó ni òun yóò gbé ọ̀rọ̀ naa lọ ile ẹjọ.

lásikò tó ń sọ̀rọ̀ lóri àbájade igbẹjọ Ademola Adeleke tó dije dupo gomina lábẹ ẹgbẹ́ PDP nípinlẹ̀ Osun nibi ìgbẹjọ to waye lánàá odé yìí ààrẹ àná Olusegun Obasanjọ sàlàyé pé ènìyàn buburu àti ẹlẹmi èṣù ní ẹni to ba ni Atiku naa maa ṣẹjọ lóri abajade èsì idibo ààrẹ.

" Mó fẹ fi asikò yìí gbóríyìn fún àwọn adájọ kóòtù fún ìgboya wọn láti ṣe ohun tó tọ, èyí jẹ igbéṣẹ̀ akọkọ nínu ìlana òfin ti ó si mú ìwúrí ba àwọn eniyan lati ni igbagbọ nínú ìgbẹjọ Nàìjíríà.

O ní ti ààrẹ Muhammdu Buhari bá le lọ si ilé ẹjọ ní ẹ̀ẹ̀mẹ̀ta láti pé èsì ìdìbò lẹjọ nígbà ti kò tilẹ̀ sí ìdí kankan láti ṣe èyí, ọmọ Naijiria tó ba ro pé wọn yan òun jẹ ni ẹtọ láti lọ si ilé ẹjọ.

"Sùgbọ́n, sí gbogbo àwọn ti wọn ti wọn ti gbìn sọ́kan ti wọn sì tun ń se igbélarugẹ àwuyewuyhe pé ti Atiku ba lọ si ilé ẹjọ ọgun àti wahala yóò bẹ silẹ̀, ibi ló ń gbe in wọn, wọn si ń wa ọ̀na àlùmọkọ́rọ́yín láti dá wàhálà sílẹ̀ ní òrílẹ̀-èdè Naàìjíríà ni."