Ohun ti ko dara ni láti maa lọ ọmú obinrin

Kinaya ko ẹyin
Àkọlé àwòrán Kinaya ni nigba ti oun wa ni omo odun mewaa ni won ti lọ omu òun mọlẹ

O ti wá ṣe pataki báyìí láti fi ẹkọ lílọ ọmu sinu ìwé ìlàna ẹkọ ilé ẹkọ alakọbẹ̀rẹ̀ fun ilanilọyẹ fún ilanilọyẹ àti láti dènà ìpalára fún awọn ọmọ obinrin.

Ajọ o n ri si ètò ẹkọ ló sọ èyí pé àṣà kí à máa fi Nkan gbigbiona pọn àyà ọmọ obinrin t ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gúnmú láti maa yọri àti kí ó maa ba wu ọkunri kii ṣe ohun to dára.

Aṣofin ilẹ̀ gẹẹsi kan Nicky Morgan sọ pe ó ṣe pàtàkì láti kọ àwọn olùkọ náà nítori wọn ní ipa pàtàkì láti kó.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionRape: Oluwaseun Osowobi ní Commonwealth fún lámì ẹ̀yẹ ọ̀dọ́ tó pegedé jùlọ ní 2018

'kò sí ààyẹ fún ẹkún'

''Kinaya" - a ti pààrọ orúkọ rẹ̀ - ilẹ gẹ̀ẹ́sì ló ń gbé

Awọn ebí rẹ̀ wá láti ìwọ -òrun ilẹ Afíríkà ní bi ti àṣà ọmú lílọ tí ṣẹ̀ wá, ò sí jẹ ọkan nínú àwọn ti ó la irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kọjá nígbà ti ó wà ní ọmọ ọdun mẹwàá.

O ní ìyá òun sọ fún òun pé " tí ǹ kò bá lọ ọmu rẹ̀ àwọn ọkunrin yóò blrẹ̀ si ni wá ọ wá láti le ba ọ ni àjọṣepọ̀"

Iyá ọmọ náà lo máa ṣe ètò ọmú lílọ yìí nígba ti wọn ba mú òkúta gbigbona tabi ṣíbi gbigbona láti fi lọ ọmu ọmọbinrin náà mọlẹ̀, wọn máà ń ṣe èyí fun bii oṣù kan tàbi jùbẹlọ

"ohun máa le gbàgbé ní irú ǹkan báyìí" kninaya sàlàyé.

"Kódà kò si ààye fún ẹkún sísun." Bí o bá sunkun ó tumọ si pé ó ti mu ìtìjú ba ẹbi náà nìyẹn "O kìí ṣe akọni ọmọbinrin"

Àkọlé àwòrán Kinaya àti ọmọ rẹ̀

Ní bayi Kinaya ti dàgbà ó si ti ọmọ ara rẹ.

Nígbà ti èyí to dágbà jùlọ pẹ ọmọ ọdun mẹwàá ìyá rẹ̀ dàbàá láti ṣe ọmu lólọ fún.

Mó sọ pé rárá, rárá, rárá, kò si ọkan ninu àwọn ọmọ mi ti yóò la ǹkan ti mo lakọja kọja nítori pe ràbàràba rẹ̀ kò ti kúrò lára mi.

Nítori náà ó kó kuro ladọ̀ àwọn mọlẹbi rẹ, nítori pe ó ni ìgbàgbọ pe èwu ńla ni ti òun ba si ń gbe pẹ̀lú wọn nítori wọn lẹ lọ ọmu ọmọ oun láì gba aṣẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Apere eni ti wọn lọ ọmu fún lasiko ti ẹgbo ba a n jina

Igbàgbọ wà wípé ó lé ni ọmọ ẹgbẹ́run kan ni wọn ti lọ ọmu fún ni ilẹ gẹẹsi.

Sùgban bi ìlanilọye ṣe ń lọ lóri abẹ dida fún ọmọ obinrin, ó ṣeni láànú pé ènìyàn péréte ló mọ nipa ọmu lílọ.