SERAP: Ìwàdìí ní ẹ̀ka iṣẹ́ ọlọ́pàá àti ìdájọ́ ló kúndùń ìwà àjẹbánu jùlọ

Awọn ọlọpa Image copyright @PoliceNG

Lánàá òde yìí ni àjọ kan ti kìí ṣe ti ijọba, Socio-Economic Rights and Accountability Project, (SERAP) ṣe agbéjade pe ,ó ṣeeṣe kí ìwà jẹgudujẹra túbọ pọ̀ si ni orilẹ̀-èdè Nàìjíríà bí ó tilẹ̀ jé pé ijọba tó ń bẹ lóde ní ǹkan ti àwọn ń koju rèé láti ọdun mẹrìn sẹ́yìn.

BBC ṣe ìwádìí lóri àbajade ìwádìí ti àjọ yiìí ṣe, láti le mọ àwọn ìgbéléwọ̀n ti wọn lò láti yọri si ohun ti wọn gbé jáde.

Igbakeji adari àjọ SERAP, Ọgbẹni Oluwadare, tó ba BBC yoruba sọ̀rọ̀ sàlàyé pé, àjọ náà ṣe ètò ìwádìí naa ní ẹkun mẹfẹfà to gbé orilẹ̀-èdè Nàìjíríà ro láàrin àwọn eeyan ti ọjọ ori wọn jẹ méjìdínlogun sóke ní ìpínlẹ̀ mẹ́fà àti olulu orilẹ̀-èdè Naijiria ti ṣe Abuja.

Àkọlé àwòrán Ipele ti ìwà jẹgudujẹra dé ni Naijiria

O ní nínú ìwádii òhun ní àwọn ti beerè ìwoye àwọn ara ilú lóri àwọn kókó tí o fi han bóya ìwa jégudu jẹra ń lọ silẹ̀ tàbí ò ń lọ sókè sí.

Awọn ẹka ti wọn fi ṣe gbèdége ayẹwo ni ẹka ọlọpàá, ẹka ètò iná ọba, èto idajọ àti ètò ẹkọ́

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKidnapped Girl: Iyá Ikimot ní lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìdààmú àti owó láti wá ọmọ náà, òun sọ ìrètí nù
Àkọlé àwòrán SERAP: Ìwàdìí ní ẹ̀ka iṣẹ́ ọlọ́pàá àti ìdájọ́ ló kúndùń ìwà àjẹbánu jùlọ

Ibèèrè náà gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ ni pé, Ẹ̀ka wó ni àwọn ènìyàn léro pé wọn le gbà rìbá ni ọwọ wọn? Iyé ènìyàn to sọ pe "ọlọpàá" jẹ ìdá mẹ́tà lé lọgọta nínú ida ọgọrun tí ìbèrè míràn tún sọ pé, ẹka wo ni àwọn ènìyàn ti san rìbá jùlọ?

Ọlọpàá náà lo tun jẹyọ, tí o si tó ìdá mẹ́rìnlelọgọrin nínú ìdá ọgọrún.

Oluwadare fí kún pé ẹka eto ìdajọ náà tún jẹ ohun to yani lẹnu bí wọn ṣe ri pé ìdá ti ohun náà ko kìí ṣe kèrèmí rárá.

Igbésẹ̀ ti SERAP ń gbe láti ṣe àdínku ba ìwá jegudujẹra

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSERAP ni ẹ̀ka ìdájọ ló gbégba oróke sìkeji

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí