Jiti Ogunye: Ẹgbẹ́ tó ní Asojúsòfin tó pójú ló lè yan Ààrẹ Ilé Asòfin àpapò

JITI OGUNYE
Àkọlé àwòrán Àríyànjiyàn ńlọ nínú ẹgbẹ́ òsèlú APC àti ẹgbẹ́ òsèlú PDP lórí ẹni tí yóò dí Ààrẹ Ilé Asòfin àpapò lórílẹ̀èdè Nàíjíríà.

Onimọ ofin ti ni iwe ofin Naijiria gbe kalẹ wi pe yiyan Aarẹ Ile Asofin Agba ati Olori Ile Igbimọ Asofin kekere fi lele wi pe aarin ara wọn ni wọn ti n yan ẹni ti yoo jẹ olori wọn.

Onimo nigba iwe ofin, Agbẹjọro Jiti Ogunye lo salaye yii lasiko to n ba BBC sọrọ lori yanpọn-yanrin to bẹ silẹ laaarin awọn oloselu lori ẹni ti yoo soju ẹgbẹ oselu lati dije Aarẹ Ile Asofin Apapọ.

Ogunye ninu ọrọ rẹ sọ wi pe ofin nikan kọ lo sakoso Ile Igbimọ wọn yii, amọ asa ati ise ti wọn la kalẹ ni wi pe ẹgbẹ to ba ni asojusofin to poju lo ma n fa ẹni to ma a se Aarẹ Ile Igbimọ Asofin kalẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOluwakaponeski ní iṣẹ́ ọmọogun ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni òun tẹ́lẹ̀ kí òun tó di aláwàdà

Onimo naa ni elẹyi to gbomi lọkan awọn ọmọ Naijiria ni ki awọn oloselu tun ilu se, ki wọn si se ilu daadaa, ki iyipada le deba awọn ọmọ Naijiria.

Jiti Ogunye fikun wi pe ilakaka awọn oloselu lati de ipo ti ma n pọju, eleyii ti ohun mu ifasẹyin ba orilẹede lapaapọ.

Onimọ ofin ti ni iwe ofin Naijiria naa kesi ẹgbẹ oselu APC lati tun ile ara wọn to, ki wọn le pa ẹnu ko fa eniyan kan silẹ lori ẹni ti yoo soju, ati wi pe ti wọn ko ba tun ile wọn to, ẹgbẹ alatako PDP le gba ipo naa mọ wọn lọwọ.

Ti a ko ba gbagbe, ẹgbẹ oselu APC pin si meji lori boya Ahmed Lawan ni yoo dije dupo tabi Sẹnetọ ali ndume ni yoo soju ẹgbẹ gẹgẹ bi oludije sipo Aarẹ Ile Asofin.