Boko Haram: Ọmọ 37,000 yóò jànfani ẹkọ́ ọ̀fẹ́ ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́ta ní ìpínlẹ̀ Borno

Ọkunrin kan n ba awọn akẹkọ ileewe kan sọrọ ni ita gbangba Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ile ẹkọ ti Boko Haram ti ṣe ọṣẹ́

Àjọ ilẹ Yuroopu tó ń ri si ipese ìrànwo ati idaabo bo ètọ ara ilú tí a mọ si European Commision's Civil Protection and Humanitarian Aid (ECHO ) pẹluu ajọṣepọ ajọ ẹlẹyinju aanu kan lorilẹede Naijiria, Plan international Nigeria ti ní àwọn ṣetan láti dáhun si ìṣòrò etò ẹkọ ti kò si fún àwọn ọmọ ìhà ìlà-òòrun ilẹ Nàìjíríà nibi ti ogun boko Haram ti gbe n ṣọṣẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJeremiah Addo: Ọmọ ọdún méjì tó ṣeeṣe kò mọ̀wé jù l'ágbàáyé

Gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpińlẹ Borno ṣe sọ, ó kéré tan, ọmọ ẹgbẹ́rún lanà mẹ́tàdínlógójì ni yóò jẹ anfani ètò ẹkọ yìí àti ààbo fún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ fún ọdún méjì ni ìjọba ibílẹ̀ Gwoza, Pulka àti Dikwa.

Níní àtẹjáde kan ti ijọba ìpiínlẹ̀ Borno fi síta sàlàyé pé ECHO ni yóò ṣe agbátẹru ètò náà.

''Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ilé ẹkọ ni àwọn agbésumọmi Boko Haram máa ń doju kọ ti wọn si mú ìfàẹ̀yin ba àwọn ọmọ ilé ẹkọ''

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOluwakaponeski ní iṣẹ́ ọmọogun ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni òun tẹ́lẹ̀ kí òun tó di aláwàdà

O ní ètò ìrànwọ náà yóò mójúto ètò ẹkọ ni kíákía, bákan náà ni yóò ṣetò ààbò fáwọn ọmọde àti àwọn ọdọ ọkunrin àti obinrin ti ìgbésumọmi dà láàmú.

Riyas Mohammed to jẹ alakoso ìdáhun pàjáwiri ni ìhà Plan International Nigeria ni " ètò ẹkọ jẹ ọkan pàtàkì nínú ǹkan ti àjọ náà ń mójú tó ní ila-oorrun Arewa Nàìjíríà. A ń ṣe ìrànwọ ètò ẹkọ ní àwọn gbùngbùn ilẹ Hausa, à ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ohun èlò ìkẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ọmọde , yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́, aga ìkọwé, pápá iṣere àti ètò ààbo fún àwọn ọmọ