Lagos: Olùkọ́ fipá bá akẹ́ẹ̀kọ́ girama lòpò nítorí máàkì

Lagos Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Akẹ́ẹ̀kọ́ obìnrin ilé iwé girama Fazir-I-Omar ní agbègbè Iwaya, Yaba ní ìpínlẹ̀ Eko ló fi ẹjọ́ olùkọ́ náà sùn ilé isẹ́ ọlọ́pàá.

Ile -isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ti fi panpẹ ọba mu oluko ile-iwe giga Fazir-I-Omar ti wọn fẹsun kan wi pe oun fipa ba awọn akẹẹkọ lọpọ.

Alukoro Ajọ ọlopaa ni ipinlẹ Eko, Bala Elkana to fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC sọ wi pe akinkanju akẹẹkọ obinrin kan lo lọ fi ẹjọ oluko naa sun, lẹyin to ni olukọ naa sọ wi pe oun ko ni jẹ ki oun tẹsiwaju lo si SS3 ti oun ko ba baalopọ.

Akẹẹkọ obinrin naa fikun fun awọn ọlọpaa wi pe igba akọkọ kọ ni yii ti olukọ naa ti ba oun lọpọ, ati wi pe SS1 ni olukọ naa ti kọkọ ba oun ni ajọsepọ, ti o si tun bere fun ibalopọ ki oun fi le tẹsiwaju lo si ipele miran.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJeremiah Addo: Ọmọ ọdún méjì tó ṣeeṣe kò mọ̀wé jù l'ágbàáyé

Elkanaa ni olukọ ti wọn fẹsun naa ni wi pe oun ko jẹbi ẹsun naa, amọ iwadii n tẹsiwaju lori isẹlẹ naa, ti awọn yoo si gbe lọ si ile ẹjo ti awọn ba ti pari iwadii naa.

Ile isẹ ọlọpaa naa wa parọwa si awọn akẹẹkọ ti iru rẹ ba ti sẹlẹ si lati tẹsiwaju wa sọ fun wọn, ati wi pe aabo wọn daju.