2019 Budget: Á ò fọwọsi àbádafofin ìṣúna láìpẹ- Bukola Saraki

Oríṣun àwòrán, @bukolasarakiofficial
Bukola Saraki ti jẹ ààrẹ ilé igbimọ aṣofin lọdun 2015
Ilé ìgbìmọ asọfin àgbà Nàìjíríà ti ṣe ìléri láti búwọlu àbádofin ètò ìṣúná ọdun 2019 lọjọ kẹrìndínlogun oṣù yìí.
Èyí wáye lẹ́yìn ti ààrẹ Buhari kọ láti búwọlu àbádofin ilé igbe ti ijọba ń kọ àti àwọn abadofin méje míràn ti àwọn aṣòfin ṣẹ̀ṣẹ̀ buwọlu.
Àyà mi kọ́kọ́ máa ń já nígbà ti mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ -Alaga iduro ọkùnrin
Ààrẹ ilé ìgbìmọ àṣofin àgbà Bukola Saraki ló kede ọ̀rọ̀ náà lásikò ìjòkò ilé.
Ó rọ àwọn ọmọ ìgbìmọ tẹ̀ẹ́koto lóri ètò ìsúná láti dá èsì pada titi ọjọ Jimọ, bákan náà lo'tún rọ wọn láti mú àbájáde wọn silẹ̀ láàrin ọjọ kẹsan an sí ọjọ kọkanla, oṣù kẹ́rin.
Ojojúmọ ní mọ ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ọmọ mi to jẹ akanda
Ilé ìgbìmọ àṣofin ti lọ fun ìsinmi ránpẹ lati pada ni ọjọ kẹsan oṣú kẹrin láti ráye moju to àwọn iṣẹ́ ìgbìmọ tẹ̀ẹ́kóto tóń móju to ìsúna owó.
Okùnrin SARS náà sọ pé òun máa pa èèyàn síbi ni- Aladugbo