Rivers Governorship Election: INEC ní Nyesom Wike ti PDP ló jáwé olúborí

INEC
Àkọlé àwòrán,

Osú tó kojá ní wọ́n sún ìdìbò tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ ń kà síwájú níbiti PDP àti AAC pẹ̀lú àtìlẹyìn APC ló ń figagbaga.

Ajọ Eleto idibo lorilẹ-ede Naijiria, INEC ti kede Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ti ẹgbẹ oselu PDP gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ni idibo sipo gomina ni ipinlẹ Rivers.

Ajọ INEC kede wipe Wike fi ibo to ju ẹgbẹrun mẹjọ ati mẹrindinlaadọrin ju oludije labẹ ẹgbẹ oselu African Action Congress AAC, Biokpomabo Awara lọ ninu idibo naa.

Awọn eleyii ti wọn ti kede ni owurọ Ọjọru lasiko ti wọn bẹrẹ kika fihan wi pe oludije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu PDP, Nyesom Wike lo n saaju pẹlu ibo to ju ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta.

Àkọlé fídíò,

Àyà mi kọ́kọ́ máa ń já nígbà ti mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ -Alaga iduro ọkùnrin

Fun ijọba ibilẹ Ogu Bolo, AAC ni ibo 814 nigba ti PDP ni ibo 11855.

Fun Obio-Akpor, AAC ni ibo 7495, nigba ti PDP ni ibo 281164.

Fun Asari Toru LGA, AAC ni ibo 18945 nigba ti PDP ni ibo 32172.

Fun Degema: AAC ni ibo 5071, nigba ti PDP ni ibo 12133.

Àkọlé fídíò,

Àyà mi kọ́kọ́ máa ń já nígbà ti mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ -Alaga iduro ọkùnrin

Ẹni to tẹle gomina Wike ninu esi idibo naa ni oludije labẹ ẹgbẹ oselu African Action Congress AAC, Biokpomabo Awara.

Àkọlé fídíò,

Jeremiah Addo: Ọmọ ọdún méjì tó ṣeeṣe kò mọ̀wé jù l'ágbàáyé

Apapọ esi idibo ti wọn ti ka ni:

PDP: 763,603

AAC: 162,180.

Awọn ijọba ibilẹ ti Ajọ INEC ti kede esi idibo naa ni Port Harcourt, Ikwerre, Andoni, Oyigbo, Eleme, Opobo Nkoro, Bonny, Okrika, Akuku Toru, Omuma, Tai, Ahoada East, Emohua, Etche ati Ogba/Egbema/Ndoni, Ogu Bolo, Obio-Akpor ati Asari Toru.

Bakan naa ni adari Ajọ INEC nipinlẹ Rivers, Ọjọgbọn Teddy Adias fikun un wi pe awọn yoo pari ikede esi idibo to ku ni irọlẹ Ọjọru.

Ti a ko ba gbagbe, Osu to kọja ni wọn sun idibo ti wọn sẹsẹ n ka siwaju nibiti PDP ati AAC pẹlu atilẹyin APC lo n figagbaga.

Àkọlé fídíò,

Okùnrin SARS náà sọ pé òun máa pa èèyàn síbi ni- Aladugbo