JAMB: Ǹjẹ́ o ma ń bẹ̀rù láti ṣe ìdańwò? wo ọ̀nà àbáyọ!

JAMB

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán,

Àjọ ìdánwò JAMB ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí àwọn tó se màgòmágó lásìkò ìdánwò láti ọdún 2009 sí 2019.

Bi igba pe eeyan de oju agbami ni idanwo a ma jẹ fun ọpọ eeyan-kii si ṣe awa nikan lagbegbe wa lọrọ yi kan.

Jakejado agbaye,idanwo ni wọn ma fi n ṣe ayẹwo bi eeyan ṣe kun oju oṣuwọn si ti a si maa fa ijakulẹ fun ẹni ti ko ba ṣe daada ninu rẹ.

Awọn akẹkọ, paapa julọ awọn ti wọn ma n kọ idanwo igbaniwole sile Ẹkọ fasiti eleyi ti ajọ eleto idanwo Jamb n dari,a maa ke irora bi idanwo naa ṣe le si ti awọn miran a si ma ni ibẹrubojo ọkan.

Ọna ki wọn ma ni ijakulẹ ninu idanwo bi Jamb,Waec tabi Neco lọpọ a ma sare titi ti wọn yoo fi tẹri sinu aburu ṣiṣe magomago.

Ọrọ magomago ti a mẹnu ba ko ṣẹyin bi Ajọ to n risi idanwo aṣewọle si fasiti,JAMB, ṣe sọ wi pe awọn yoo bẹrẹ iwadii lori awọn to ti ṣe JAMB lọna ẹru sẹyin , abi ti ẹlomiran ba wọn ṣe.

Jamb ni awọn yoo fi oju wọn han ti wọn si le padanu anfaani iwe ẹri wọn koda ko jẹ wi pe wọn ti pari Ẹkọ sẹyin laarin ọdun 2009 si 2019.

Ki wa ni ọna abayọ lati koju ibẹru lasiko idanwo tabi lati yago fun magomago lasiko idanwo?

Àkọlé fídíò,

Irokotọla: Báwo ló ṣe rọrùn láti fi àmì sí ọ̀rọ̀ yìí, ‘Irokotọla’

Ki ni ọna lati koju ibẹru lasiko idanwo?

Onimọ nipa ihuwasi eniyan, Racheal Olaniyan lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ sọ nipa awọn ohun ti o ma n mu ki awọn eniyan ṣe aṣemaṣe lasiko idanwo.

Ninu ọrọ rẹ, Olaniyan sọ wi pe ẹru ati ibẹrubojo ma a n fa a ki awọn eniyan ṣe aṣemaṣe lasiko idanwo.

Imọran rẹ re e fun yin:

  • Ri wi pe o ka iwe nipa idanwo naa ni ojoojumọ lati le ṣe igbaradi to peye.
  • Sun daradara ni alẹ ọjọ idanwo rẹ nitori aisun ma n fa ipaya fun awọn ẹlomiran
  • Iroyin ṣe koko lasiko idanwo, ri daju wi pe o mọ gbogbo ohun to yẹ ko o mọ nipa ibi ti idanwo naa yoo ti waye ati akoko ti yoo waye, eyi le fa ipaya ti o ba di ọjọ idanwo ki eniyan to mọ, oṣeeṣe ki gbogbo iwe ti eniyan ka fo lọ ti ko ba ni imọ nipa ibi ati akoko ti idanwo naa yoo waye.
  • Mọ ohun to ma n jẹ ki o paya lasiko idanwo, ki o si ri wi pe gbogbo rẹ lo wa ọna abayọ si
  • Ri wi pe , o sọ ọrọ iwuri si ara rẹ lasiko idanwo . Yin ara rẹ fun aṣeyori ti o n se lọwọlọwọ ati bi o ṣe n dahun ibeere idanwo naa.
  • Ero buruku ma n fa ipaya lasiko idanwo, ri wi pe o mu ero ti ko dara kuro lọkan lasiko idanwo naa.
  • De aago ọwọ lasiko idanwo, lati le mọ igba ati akoko ti o fẹ lo lori ibeere kọọkan lasiko idanwo naa.
  • Lasiko idanwo naa, sinmi bi isẹju aaya lati le ronu si ohun ti o fẹ kọ.
  • Bẹrẹ lati dahun ibeere to wa ninu idanwo rẹ nipa ki koju si awọn eleyi ti o mọ daada ki o si ṣe iyoku lẹyin rẹ
  • Lakotan, ti o ba ri wi pe ko si ọna abayọ si ibẹru-bojo ti o ma n mu o lasiko idanwo, ri wi pe o koju si ile iwosan lati gba itoju lọwọ dokita ati onimọ nipa ihuwasi eniyan.