South Africa Election: Ẹgbẹ́ òsèlú 50 ló ń kópa nínú ìdìbò

South Africa
Àkọlé àwòrán Ààrẹ Cyril Ramophosa láti ẹgbẹ́ òsèlú ANC náà ń díje dupò láàárín orísirísi ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu nínú ẹgbẹ́ òsèlú náà.

Ọdun mẹẹdọgbọn ni yii ti orilẹede South Afirica gba ominira, eleyii to faye silẹ fun iran gbogbo to wa lorilẹede naa lati dibo yan ẹni ti o ba wu wọn.

Ẹgbe oselu African National Congress (ANC) to ja fun ominira awọn eniyan dudu lorilẹede naa lo ti wa lori aga iṣejọba orilẹede ohun lati ọdun 1994.

Ninu idibo yii, awọn oludibo yoo ma dibo yan awọn aṣojusofin lati ẹgbẹ oṣelu to wu wọn, nigbati awọn aṣojusofin yii yoo wa lọ dibo yan aarẹ.

Idibo ti yoo gbe iṣejọba tiwantiwa wọle fun saa kefa, n waye lasiko ti awọn eniyan n binu lori ẹsun iwa jẹgudugẹra to kaakiri, ọrọ aje to dẹnu kọlẹ ati ọrọ ilẹ ni orilẹede naa.

Ẹgbẹ oselu meji ti o n koju aarẹ Ramophosa ti ANC ni Democratic Alliance (DA) ati Economic Freedom Fighters (EFF).

Ohun to yẹ ko mọ nipa idibo South Africa

  • 26.76 miliọnu eniyan lo forukọsilẹ lati dibo
  • Ida 55% ninu wọn jẹ obinrin
  • Ẹgbẹ oṣelu mejidinlaadọta lo n dije dupo.
  • 28,757 ni agbegbe ti idibo yoo ti ma a waye.
  • 220,000 ni osisẹ ajọ to n bojuto eto idibo gbogboogbo yii
  • Amọ, ọdọ to to miliọnu mẹfa ni ko ni kopa ninu idibo naa.

Related Topics