EFCC: A fẹ́ mọ bí Saraki ṣe gb'owó osù gómìnà, ààrẹ ilẹ́ asòfin

Saraki-EFCC Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ààrẹ Ilé Ìgbìmọ̀ Àsòfin. Bukola Saraki ti sọ fún Àjọ EFCC pé kí wọ́n fi òun sílẹ̀, kí wọ́n yé é dìtẹ̀ mọ́ òun.

Ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra lorilẹede Naijiria, EFCC ti kesi Aarẹ Ile Igbimọ Asofin Agba, Bukola Saraki wi pe ko ni ohunkohun lati bẹru ti ko ba ti hu iwa ibajẹ.

Adari Eto Iroyin Ajọ EFCC, Tony Orilade ninu atẹjade to fi lede sọ wi pe ajọ naa n ṣewadii gbogbo owo to gba gẹgẹ bi owo osu lasiko to jẹ gomina ni ipinlẹ Kwara ati eyi to gba lasiko to jẹ aarẹ Ile Igbimọ Asofin.

Orilade ni awọn ni ẹsun iwa ibajẹ ati ajẹbanu lorisirisi ti wọn fi kan Bukola Saraki, nitori naa wọn rọ ọ lati jẹ ki wọn se isẹ wọn gẹgẹ bi ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ.

Ajọ EFCC ni ki Saraki ranti pe awọn ni asẹ labẹ ofin ati ibura lati ri wi pe awọn fi opin si iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria.

Amọ, aarẹ ile asofin naa nigba to n fesi ni ibanilorukọjẹ ni ohun ti ajọ EFCC n se, ati wi pe ohun ko ṣẹ ẹsẹ kankan, wọn kan n ditẹ mọ oun ni.