Awujale: Gómìnà Amosun kò fẹ́ràn àwọn ará Ìjẹ̀bú

AWUJALE-AMOSUN Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Ọba Awujale ti ìlú Ìjẹ̀bu ní bí ó tilẹ̀ jẹ́pẹ́ ọ̀rẹ́ ni òun àti gomina, àmọ́ kò ní ìfẹ́ àwọn ènìyàn òun rárá.

Awujale ti ilu Ijebu, Ọba Sikiru Kayode Adetona ti ni gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun ko fẹran awọn ara Ijebu rara.

Ọba Awujalẹ sọ eyi ni ibi ti o ti n sọrọ lori akọtan ọrọ isejọba abẹle lorilẹede Naijiria, ni Ile Iwe giga Ọlabisi Ọnabanjo, to kalẹ si Ijebu Ode, ni ipinlẹ Ogun.

O ni bi bi o tilẹ jẹpe ọrẹ ni oun ati gomina, amọ ko ni ifẹ awọn eniyan oun rara, nitorina ko ni ifẹ oun tikalara niyẹn.

Awọn eniyan to wa ni ibi ti awujale ti sọ ọrọ yii fi atẹwọ yẹ ọba naa si.

Amọ gomina ipinlẹ Ogun naa ko si nibi ayẹyẹ naa lati fesi si oun ti awujalẹ sọ.