CBN: Kò sí owó tó sọnù ní banki àpapọ̀ Naijiria

EMEFIELE Image copyright WIKIPEDIA
Àkọlé àwòrán Fọnran kan fẹsun kan gomina banki apapọ Naijiria ati awọn alabasisẹ rẹ ti wọn n wa ọna lati bo 500bn Naira ti wọn ji.

Banki apapọ lorilẹede Naijiria, CBN ti sọ wi pe ko si owo to sọnu ni banki apapọ, lẹyin ti fọnran kan gbe e jade wi pe wọn ji ẹẹdẹgbẹta bilioọu Naira ni apo ijọba.

CBN lori ẹrọ ikansiraẹni Twitter wọn bu ẹnu atẹ lu fọnran naa wi pe ko si owo to sọnu ni apo banki apapọ Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Lórí iṣẹ́ ikàn yìí, a ti kọ́ ilé, ọmọ ti lọ ilé ìwé'

Amọ, fọnran naa gbe jade wi pe Gomina CBN, Godwin Emefiele pẹlu igbakeji ati adari eto isuna ni ẹka banki apapọ lori ọna ti wọn yoo gba fi di owo ti wọn ji ni apo ijọba ti ko ni fi ba eto ọrọ aje orilẹede Naijiria jẹ.