Zainab Aliyu ti tààjò dé ariwó modúpẹ lọ́wọ́ ọlọhun ló n ké
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Zainab Aliyu: Orílẹ̀èdè Saudi túu sílẹ̀ lẹ́yìn oṣù mẹ́rin tó ti wà ní àhámọ́

Ọmọbinrin, ọmọ orilẹede Nàìjíríà, ẹni ọdún méjìlélógun ti wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ fí sílẹ̀ ní àhámọ ni Saudi Arabia, Zainab Aliyu, tí balẹ̀ si ìlú Kano báyìí

Ní kété tó balẹ̀, ẹkún ayọ̀ ló mu bọnu lẹ́yìn to rí àwọn mọ̀lẹ̀bi rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló ń kígbe "Ọlọ́hun mo dúpẹ", "Ọlọhun mo dúpẹ́", kò sọ ǹkankan ju ariwo Ọlọ́hun mo dúpẹ́ lọ.

Bààlú to gbé Zainab dé láti Jeddah, Saudi Arabia balẹ̀ si pápákọ̀ Aminu Kano ní ǹkan bíí ààgo mẹ́wàá ààrọ̀ òní ọjọ́ ajé, ti asoju orilẹ̀-èdè Nàìjíríà ni Jeddah Garba Satomi Grema sì tèlée ọmọ náà wálé.

Gbogbo àwọn mọ̀lẹ́bi, ọ̀rẹ́ àti alábagbé Zainab ni wọn dúro ni pápákọ̀ ofurufu làti kíii káàbọ lẹ́yìn oṣ mẹ́rin to ti wà ni ẹwọn ní Saudi Arabia.

Ọjọ́ kejìdílọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdun 2018 ni àwọn alásẹ Saudi ti mú Zainab sẹ́wọn nígbà ti []oun , màmá àti ẹgbọ̀n rẹ̀ jọ lọ fún Umrah, ni Saudi Arabia, ti wọn si ni wọn ká òògunolóró mọ inú ẹrẹ̀ rẹ̀.

Bàbá rẹ̀, Alhaji Habib Aliyu tó ba BBC sọ̀rọ̀ sàlàyhe pe ọkàn Zainab wúwo báyìí yóò s]i gbà wọn lásikò diẹ̀ ki ọkan rẹ̀ to le balẹ̀ ti yóò si bs sípò.

"Ẹkún ló kàn ń sun láti ìgbà to ti dé , kò tilẹ̀ le sọ ohunkohun, sùgbọ́n lẹ̀yìn ìgbà díll mo nígbàgbọ́ pé yóò pada bọ sípò. A dúpl lọ́wọ́ Ọlọhun fún anfàni ti a ri gbà à sí dúpẹ̀ lọ́wọ́ gbogbo yín."