Leah Sharibu ti lo irínwó ọjọ́ ní àhámọ́ Boko Haram

Akara oyinbo fun ọjọ ibi Leah Sharibu Image copyright Google, BBC
Àkọlé àwòrán Akara oyinbo fun ọjọ ibi Leah Sharibu

Leah Sharibu ti awọn agbesunmọmi Boko Haram jigbe ni ọdun to kọja, ti pe ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni panpẹ wọn.

Leah Sharibu wa lara awọn ọmọbinrin ile iwe Dapchi ti ikọ agbesunmọmi Boko Haram jigbe ni Osu Keji, ọdun 2018, amọ ti wọn ko lati fi silẹ nitori o kọ lati kọ ẹsin kristẹni silẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBoko Haram yóò dá Leah sílé

Gẹgẹ bi ẹni se jẹ ọjọ ibi rẹ, awọn eniyan pejọ si ile ijọsin lati se ẹsin ọjọ ibi fun ọmọ naa to duro sinsin lori igbagbọ rẹ.

Lori ọju ẹrọ ibaraẹnisọrọ Twitter ni awọn eniyan ti ki Leah ku ọjọ ibi rẹ.

Àkọlé àwòrán Leah Sharibu wa lara awọn ọmọbinrin ile iwe Dapchi ti ikọ agbesunmọmi Boko Haram jigbe ni Osu Keji, ọdun 2018.

Bakan naa ni ọgọọrọ eniyan ni ilu Abuja parapọ lati se ifẹhọnu han pe ki ijọba orilẹede Naijiria ri wi pe wọn gba itusilẹ Leah Sharibu ni kiakia.

Àwọn ìròyìn míì tí ẹ lè nífẹ sí

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Bí ìrẹsì tèmi Ayinde bá ń pàkùta, kò tọ́ sẹ́nu aláàrù Barrymaade'