SERAP: Àwọn olósèlu ń fojú ará ìlú gbolẹ̀ pẹlu owó tí wọ́n bù fún ara wọn

Ile igbimọ asofin naijria

Lẹyin ti ajọ ajafẹtọ ti a mọ si SERAP pinnu lati gbe ile igbimọ aṣofin Naijiria lọ ile ẹjọ lori biliọnu mẹrin ati aabọ ti wọn ni awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin tuntun (9th National Assembly) yoo gba, ajọ naa ni awọn ko ni dawọ duro nibẹ; wọn ni o ṣeeṣe ki wọn tun gbe ileeṣẹ aarẹ lọ ile ẹjọ naa.

SERAP ni awọn owo nla ti awọn aṣofin ati ileeṣẹ aarẹ n bu fun ara wọn jẹ oun abuku fun Naijiria.

Adari ajọ SERAP Adetokunbọ Mumuni sọ fun BBC Yoruba wipe kii ṣe awọn aṣofin tuntun yii nikan ni yoo gba owo yanturu bi saa iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari ti 2015 si 2019 yii ṣe n pari.

Owo ti awọn aṣofin naa yoo gba gẹgẹ bii owo ikinikaabọ bọ si N9,926,062.5 fun aṣofin kọọkan ni ọmọ Naijiria ti bẹnu atẹ lu eyi to mu ki ajọ SERAP sọ lori Twitter wi pe awọn n lọ ile ẹjọ lori ọrọ naa.

Mumuni sọ pe, "A ko ni da ẹnu duro lẹyin ti a ba gbe awọn aṣofin lọ ile ẹjọ. Ọmọ Naijiria ko le maa jiya ki awọn oloṣelu maa bu owo fun ara wọn bo ṣe wu wọn. Wọn kan n foju ara ilu gbolẹ nikan ni."

Nigba ti akọroyin wa beere idi to fi jẹ wipe awọn aṣofin nikan ni wọn n sọrọ nipa nigba ti awọn oloṣelu to wa labẹ ileeṣẹ aarẹ naa n gba owo yanturu, adari SERAP naa ni lẹyin ti awọn ba pe awọn aṣofin lẹjọ tan, awọn yoo tun gbe igbeṣẹ lori ti ileeṣẹ aarẹ.

Image copyright dailypost

Ọjọru ni ajọ SERAP ke pe awọn ọmọ Naijiria ti ọrọ naa ba bi ninu lati fi orukọ wọn ranṣẹ ki awọn le fi orukọ wọn sara awọn to n pe ijọba lẹjọ lori ọrọ naa.

SERAP ni owo tabua-tabua ti awọn aṣofin bu fun ara wọn naa lodi sofin.

Bẹẹ si ni awọn ọmọ Naijria ti n fi ero wọn han lori ọrọ naa lori ayelujara, nibi ti wọn ti n sọ fun gbogbo eniyan ki wọn tu jade lati fi ẹhonu han lori ọrọ naa.

Ọrọ owo awọn aṣofin yii hande lẹyin ti ọpọlọpọ ipinlẹ Naijiria ti ni awọn ko lagbara lati san ẹgbẹrun lọna ọgbọn owo oṣu oṣiṣe ti Owó dé! Ilé Aṣòfin Àgbà fòǹtẹ̀ lu N30,000 owó oṣù òṣìṣẹ́ni oṣu meji ṣẹyin.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSaraki dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀