Toma Unu: Ọmọbìnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ ya àwọran
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Toma Unu: Ọmọbìnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ ya àwọran nítori pe ó ni ìpènija ọpọlọ

Toma, ọmọbinrin tó n fi ẹṣẹ rẹ̀ ya àwọran tó jojú nigbese. Toma Unu jẹ ẹni ìwúrí pẹ̀lú bí kò ṣe ro ti ìpèníjà rẹ̀ tó sì ń ṣe ohun ribi ribi to tayọ òye ènìyàn.

Láti ǹkan bii ọgbọn ọdun ni Toma tí ń ba àìsàn to jẹ mọ ọpọlọ yí nítori pe bẹ́ẹ̀ ni wọn se bii.

Sùgbọ́n nígbà ti ó ri pe òun ko le lo ọwọ oun, ló ba bẹ̀rẹ̀ si ni kọ́ bi wọn se n fi ẹsẹ se orisirisi ǹkan; o le fi jẹun, tẹ fóònù, bákan náà lo fi n ya aworan.

Toma sọ pe ọlọrun ni ayaworan àkọkọ àti pe yiya aworan ti ran oun lọwọ láti fi èrò ìnu oun han ní ọpọ igba.