Ní Ìpínlẹ̀ Ogun, Ọmọ ọgbọ̀n ọdún fi àdá bẹ́ ikùn bàbá rẹ̀ ̀

BAbatunde Olagesin ti wọn fẹsun ipaniyan kan Image copyright Punch

Ọwọ ọlọpaa Ipinlẹ Ogun ti tẹ arakunrin kan Babatunde Olagesin, ẹni ọgbọn ọdun kan ti wọn fi ẹsun kan wipe of fi adá bẹ́ ikùn baba rẹ ni ilu Ijoko, Ipinlẹ Ogun.

Iroyin ni ija bẹ silẹ laarin baba naa, Taiwo Olagesin ati ọmọ rẹ nigba ti Babatunde ni oun fẹ lọ ṣiṣẹ owo ni Oshodi, Ipinlẹ Eko.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Abimbola Oyeyemi sọ wipe oloogbe naa lo fa ada yọ lati fi dẹrun ba ọmọ rẹ. O ni nigba ti wọn jọ wọya ija ti wọn si n du ada mọ ara wọn lọwọ ni ada naa fa oloogbe naa nikun ya.

Oyeyemi ni Babatunde wa ni ahamọ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣe iwadi ẹsun ipaniyan to wa ni Eleweran, Abeokuta.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSunday Ayẹni: Damilọla, aya ọmọ mi fìgbónára sọ mi sókùnkùn alẹ́

Awọn aladugbo sọ wipe idi ti baba naa ko fi fẹ ki ọmọ rẹ jade ni wipe o ni oun fẹ ki o tẹle oun lọ ṣiṣẹ kan.

Afẹsunkan naa sọ fun awọn ọlọpaa wipe oun ko mọọmọ pa baba oun.

Awọn aladugbo ti wọn ti gbiyanju lati la ija ki ọfọ naa to ṣẹ sọ wipe awọn gbiyanju lati gbe oloogbe naa lọ ile iwosan bi ẹjẹ ṣe n tu lara rẹ ṣugbọn o gbẹmii mi loju ọna.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí: