Atiku Vs Buhari: Bulkachuwa yọra rẹ̀ nínu ìgbẹ́jọ́ èsì ìdìbò ààrẹ

Adajọ Bulkachuwa

Lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye to rọ mọ wiwa ninu igbimọ ti yoo gbẹjọ esi idibo aarẹ Naijiria to waye ni oṣu kẹta ọdun yii, Aarẹ Ile Ẹjọ Kotẹmilọrun, Adajọ Zainab Bulkachuwa, ti yọ ara rẹ ninu igbẹjọ naa.

Ẹgbẹ oṣelu PDP kọwe mọ wipe kò yẹ ko wa lara igbimọ naa nitori wipe ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni ọkọ rẹ ati wipe, o ti kọwe fi igbimọ naa silẹ ni Ọjọru.

Ọkọ adajọ naa, Adamu Bulkachuwa jẹ sẹnetọ ti wọn ṣẹṣẹ yan labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, ti ọmọ rẹ naa si jẹ oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu naa.

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni adajọ naa n ṣegbe lẹyin APC.

Bo tilẹ jẹ pe igbimọ naa ti ni ko si ootọ kankan ninu wi pe Bulkachuwa n ṣ'egbe lẹyin APC nitori awọn ẹbi rẹ, o ni oun yọ ara oun ninu igbimọ ẹlẹni marun un naa fun idi ti oun ko ni sọ.

O ni inu oun dun wipe ọrọ naa ti ni iyanju gẹgẹ bi ilana ofin ṣugbọn oun ko fẹ ki adajọ obinrin miiran foju ri oun ti oun ti koju.

Adajọ naa tun fi han wipe ẹlomiiran yoo rọpo oun ninu igbimọ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionObasanjo: Atiku kìí se Áńgẹ́lì, àmọ́ yóò se dáadáa ní ìlọ́po méjì ju Buhari lọ