PDP: Àrà tó bá wu Gomina Ajimobi kó dá lọ́sẹ̀ kan tó kù yìí

Abiola Ajimobi Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Gomina Ajimobi ti yóò fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́nu ọjọ́ diẹ sí ìsìnyín ló sẹ̀sẹ̀ yan olórí òsìsẹ́ tuntun ní ìpínlẹ̀ Ọyo.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ oselu PDP ti ni igbesẹ Gomina Ajimobi lori bi o se yan olori osisẹ tuntun ko di awọn lọwọ ninu eto ti awọn ni silẹ.

Akeem Olatunji to jẹ agbẹnusọ fun ẹgbẹ oselu PDP ni gomina Ajimobi lo si wa lori oye, bẹẹ lo si ni anfaani lati se ohun to wu u.

Olatunji ni awọn ko le e sọ pe awọn fọwọ si igbesẹ naa tabi awọn ko fọwọ si i, ṣugbọn awọn yoo wo igbesẹ naa finifini ti awọn ba de ipo, lati wo boya ọna to gba de ipo ba ofin mu gẹgẹ bi akowe agba tabi bẹẹ kọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionContortionist: Mo lè gbé ìfun mi pamọ́ ki n tún se èémí!

O fikun un pe ohun to wu gomina naa lo n se nipinlẹ naa, amọ ko da eto ẹgbẹ oṣelu PDP to jawe olubori ninu idibo to kọja ru nitori ẹka osisẹ yato si eto oselu lorilẹ-ede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIjó Bàtá ti Yorùbá gb'oríyìn ní Calabar Festival 2018

Ti a ko ba gbagbe, ni Ọjọru, ọsẹ yii ni gomina Abiola Ajimobi yan abileko Ololade Agboola gẹgẹ bi adari awọn osisẹ tuntun, lẹyin ti abileko Hannah Ogunnesan ko iwe fi ipo silẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionColorado ni Amẹrika àti odò Awaye ní Naijiria nikeji àdágún órí àpáta ní gbogbo àgbáyé!