Aisha Buhari: Ìpínlẹ̀ Kano kò rí ànfàní ètò ìjọ̀ba Buhari jẹ.

Aisha Buhari aya Aare Nigeria

Oríṣun àwòrán, Aisha Buhari

Àkọlé àwòrán,

Aisha Buhari: Aya ààrẹ orilẹ̀-èdè Naijiria ke gbàjare lori eto ijoba Buhari

Aya ààrẹ orilẹ̀-èdè Nàìjíríà Aisha Buhari ni àwọn eto oṣelu ti ijoba Muhammadu Buhari ṣe ni sáà àkọ́kọ́ rẹ̀ kò ṣe ànfani fún àwọn obinrin ní ìhà Aríwá orilẹ̀-èdè Naijiria.

Aisha sọ̀rọ̀ náà lásìkò tó ń ṣepàdé pẹ̀lú àwọn obinrin kan ni ilé ijọba ní'lú Abuja lọ́jọ́ Abamẹta tí ó sì ń wá ìdáhùn si ọ̀nà ti ìjọba gbà pín owó ti wọ́n ń fún àwọn ìdíle tó tòṣì júlọ láwọn ìpínlẹ̀.

Àkọlé fídíò,

Ìdílé tó gba olùkọ́ èdè Yorùbá fún àwọn ọmọ nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

O ní owó ti wọn ni wọn fi rà àwọ̀n apẹ̀fọn kìí ṣe èyi to ṣee gbọ́ séti rárá.

'' Wọn ni wọn ti ná mílíọ̀nú mẹ́rìndílógun dọ́là láti ra àwọ̀n apẹ̀fọn. Kò yé mí sùgbọ́n bóyá ó yé ẹlòmíràn, bóyá ìrònú tèmi nìkan ló gbà bẹ́ẹ̀ ni, mílíọ̀nú mẹ́rìndínlógun dọ́ọ́là tó láti fí gbogbo orilẹ̀-èdè Naijíríà,'' Aisha ló sọ bẹ́ẹ̀.

Olùbádamọràn pàtàki ààrẹ lóri ọ̀rọ̀ owó amúludùn Maryam Uwais kéde lọ́jọ́bọ̀ ọjọ kẹtàlélógun osù karun ọdun 2019 pé ìjọba ti ṣe àgbéjade owó láti pèsè gbogbo ètò rẹ̀ lóri mímú ti àwọn alaini gbọ láwujọ, èyí to pín si ẹ̀ka mẹ́rin, N-Power, pínpín owó fún àwọn to toṣi jùlọ, fífún àwọn ilé ìwé alákọbẹ̀rẹ̀ lóúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan lójúmọ àti rírọkun sápá àwọn olókoowò kékèké (GEEP).

Oríṣun àwòrán, Aisha Buhari

Àkọlé àwòrán,

Aisha Buhari: Aya ààrẹ orilẹ̀-èdè Naijiria ke gbàjare lori eto ijoba Buhari

O ní "mó rò pé ó yẹ kí wọn lo onírúurú ọ̀nà láti pín ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tá bílíọ̀nù Naira láti ṣe àṣeyori lori ètò náà, ṣùgbọ́n ìlànà ti wọn lò kò yé mi rárá. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ní ìhà àríwa ni ko ri owó yìí gbà, kò yé mí oo bóyà àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ tiyín ri owó náà gbà"

O ní lóòtọ́ ó ṣiṣẹ́ dáada ní àwon ìpínlẹ̀ mìíràn, nítorí oriṣiriṣi ọ̀nà ni wọn gbé e gbà.

O fí kún-un pé " ní ìpínlẹ ti èmí ti wá, ìjọba ìbílẹ kan péré ló jẹ ànfàní rẹ̀ nínú ìjọba ìbílẹ̀ méjìlélógun tó wà níbẹ, mí ò bèrè ǹkan to ṣẹlẹ̀ mí ò si fẹ́ mọ.''

Iyawọ ààrẹ fi kún pé nínú ìwòye òun, ìpínlẹ̀ Kano ló buru jù nínú àwọn ìpínlẹ̀ ti kò jẹ ànfani owó náà.