#Adewura Latifa Bello: Ọlọ́pàá ní àwọn kò tíì lè fídí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun ni

Lateefat Bello lori iduro
Àkọlé àwòrán,

Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ onímọ̀ ìṣirò owó ni Lateefat, ẹni ọmọ ọdún mẹ́rìndinlọgbọ̀n

Adewura Latifat Bello, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ti wọ́n ń wá láti ọjọ́ kẹẹ̀dógún, oṣu karùn ún ọdún 2019 lásìkò tó ń padà lọ sílé láti ibiṣẹ́ lágbègbè Gowon Estate ní wọ́n ti rí báyìí.

Wọ́n rí Adewura nínú adágún omí ńlá kan lẹ́yìn ti òkìkí tàn kálẹ̀ pé wọ́n ń wá.

Ọmọbìnrin náà ní àwọn ara àdúgbò naa gbe sórí ẹ̀rọ ayélujára pé àwọ̀n ri ninu àgbàrá òjò.

Wọn ni eyi ṣẹlẹ lẹ́yìn ti wọn ti gbà wọ̀n ní ìmọ̀ràn láti máa tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò wọ́n lọ́jọ́ náà, sùgbọ́n ní kété ti wọ́n tẹ̀síwájú ni àgbàrà òjò gbá ọmọbìnrin náà lọ àmọ́ orí kó ọlọ́kadà yọ.

Àkọlé fídíò,

Ẹgbọ́n olóògbé Suga: Wọ́n yìnbọn fún Suga lójú mi, n kò sì lè dá wọn dúró

Ní kété ti wọ́n rii ni wọn fa ọlọ́kadà náà lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá ti agbegbe Mọṣálásí ti wọ́n si rọ ẹbí ọmọ náà láti ṣe àbẹwò si àgọ ọlọ́pàá láti jẹ́ kí ọlọ́kadà ọhun ṣàlàyé ìrú ẹni tó gbé.

Èyí ní ẹbi Adewura ṣe ti wọ́n fi rí òkú Adewura ní inú adágún omí ǹlá (Canal) ní àgbègbè Iyana Ipaja ni ipinlẹ Eko.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, agbẹnusọ ọlọ́pàá, Bala Elkana sọ fún àwọn akọ̀rọ̀yìn pé, kò tii sí àrídájú pé òkú Adewura ní wọn ri àfi ti ìwádìí ba parí níwọ̀n ìgbà to jẹ́ pe òkú rẹ̀ ti ń jẹra.

Àkọlé fídíò,

'Ohùn gooro ló gbé mi dé ọ̀dọ̀ ààrẹ̀ Bush, Obama, Obasanjo, Goodluck, Buhari'

Ó ní "lóòtọọ́ a rí òkú kan ní inú adágunní Ipaja ṣùgbọ̀n a kò tíì le fi ẹnu ọ̀rọ̀ jóná báyìí nítorí òkú rẹ̀ ti ń jẹrà.

Àkọlé fídíò,

'Àsìkò Amojúẹ̀rọ Seyi ni ló fi wọlé l'Oyo, kìí ṣe àsìkò èmi Omobolanle'

Orọ awọn agbofinro ni pe:

"Lọ́wọ́ ti a wà yìí, ìgbẹ́kèlẹ̀ ọlọ́pàá ni abájáde ǹkan ti àwọn oníṣègùn oyinbo bá sọ lẹ́yìn àyẹwò wọ́n, nítori à ti gbé òkú náà lọ si ilé ìwòsàn fún àyẹwò".

Àkọlé fídíò,

Toma Unu: Ọmọbìnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ ya àwọran nítori pe ó ni ìpènija ọpọlọ

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ti ń ṣelédè lẹ́yìn ọmọbìnrin náà lójú òpó Twitter

Àkọlé fídíò,

Contortionist: Mo lè gbé ìfun mi pamọ́ ki n tún se èémí!