Peter Mutharika di ààrẹ ilẹ̀ Malawi lẹ́ẹ̀kejì

Peter Mutharika
Àkọlé àwòrán,

Ẹni tó ń ba ààrẹ du ipò Lazarus Chakwera tó se ipò kejì bu ẹnu àtẹ́ lu ìdájọ́ náà lórí ẹ̀sùn màgòmágó lásìkò ìdìbò.

Aarẹ orilẹ-ede Malawi, Peter Mutharika ni awọn eniyan ti di ibo yan fun saa keji pẹlu ibo to le ni ida mejidinlogoji.

Mutharika to jẹ ẹni ọdun mejidinlọgọrin ọhun lo wa ni ipo gẹgẹ bi aarẹ, ti awọn eniyan si tako idibo to waye ni Ọjọ kọkandinlogun, Osu karun un, ọdun yii pẹlu igbakeji rẹ.

Ọjọ Aje ni esi idibo naa jade lẹyin ti ile ẹjo gbesẹ kuro lori esi idibo naa.

Àkọlé fídíò,

Afeez Agoro: O ṣòro fún mi láti wọ Danfo jáde

Ẹni to n ba aarẹ dupo, Lazarus Chakwera to se ipo keji bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu idajọ naa lori ẹsun magomago lasiko idibo.

Àkọlé àwòrán,

Ọjọ Aje ni esi idibo naa jade lẹyin ti ile ẹjo gbe idina kuro lori esi idibo naa.

Àkọlé fídíò,

'Àsìkò Amojúẹ̀rọ Seyi ni ló fi wọlé l'Oyo, kìí ṣe àsìkò èmi Omobolanle'

Ọpọlọpọ eniyan lo ri idibo naa gẹgẹ bi ẹni yii ti ko si ẹni to le sọ bi esi idibo naa se ma a ri.

Bakan naa ni Olori Ajọ to n risi eto idibo lorilẹ-ede Malawi, Jane Ansah, ti parọwa fun ki gbogbo nkan wa ni irọwọrọsẹ lorilẹ-ede naa.

Àkọlé fídíò,

Bode George: òòtọ́ ni ìkìlọ̀ Obasanjọ ati Soyinka