Buhari: Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ aláàbò, ẹ ṣe ohun tó yẹ láti pèsè ààbò tó péye

Nigeria Image copyright Google
Àkọlé àwòrán Adari awọn ologun oju omi ni aarẹ Buhari ti gbe igbimọ kalẹ ti yoo ma risi oro eto aabo to mehe lorilẹede Naijiria.

Aarẹ orileede Naijiria, Muhammadu Buhari ti pasẹ fun awọn ẹsọ eleto aabo lorilẹede Naijiria, lati dẹkun bi awọn eniyan kan se n ko ohun ija wọ orilẹede Naijiria lọna ẹburu.

Adari ikọ ọmọogun oju omi orilẹede Naijiria, Ọgagun Ibot-ete Ibas lo sọ bẹẹ fun awọn akọroyin, ni ile aarẹ ni Abuja, lẹyin ti Aarẹ Buhari se ipade pọ pẹlu awọn adari ile isẹ ọmọogun Naijiria.

Ibas ni, inu aarẹ Buhari dun si igbesẹ awọn ẹsọ eleto aabo lorilẹede Naijiria pẹlu akitiyan wọn lati bori ikọ agbesunmomi ati eto aabo to mẹhẹ kaakiri ẹkun to wa lorilẹede naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLagosians: Eni tó ní owó ló ń kọ Will

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọgaagun awọn ọmọogun ori omi naa wa fikun wi pe, aarẹ Buhari rọ gbogbo awọn ti ọrọ naa kan lati ri daju pe wọn se ohun gbogbo to yẹ lati mu eto aabo gboro si lorilẹede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAlapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?