Europa League Final: Chelsea lu Arsenal ní àlùdákú ní Baku.

SEad Kolasinac ati Mesut Ozil Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iya jẹ Arsenal

Alubami ni ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea na Arsenal pẹlu ami ayo mẹrin si ẹyọ kan ni ifẹsẹwọnsẹ asekagba ti Europa League fun ọdun 2019.

Agbabọọlu Chelsea, Giroud lo kọkọ si san bantẹ iya fun Arsenal to jẹ ikọ rẹ tẹlẹri, ki Pedro ati Hazard to pari iya naa fun Arsenal.

Amo, Alex Iwobi ti Arsenal naa ko jẹ ki iya naa ko jẹ awọn gbe, bẹẹ lo da ẹyọkan pada fun Chelsea, ti ayo naa si pari si 4-1.

Igba kẹfa niyi ti ikọ agbabọọlu Chelsea yoo ma koju Arsenal ni ifẹsẹwọnsẹ to jẹ asekagba Europa League.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Chelsea v Arsenal,

Chelsea vs Arsenal, gbẹgẹdẹ yóò gbiná ní Europa League Final!

Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ti kuna ni igba mẹrin ninu maarun, ti wọn ti de asekagba idije naa, ti wọn si jawe olubori ni 1994 CWC.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Agbabọọlu Chelsea, Giroud lo kọkọ si san bantẹ iya fun Arsenal to jẹ ikọ rẹ tẹlẹri, ki Pedro ati Hazard to pari iya naa fun Arsenal.

Bakan naa ni ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ti jawe olubori fun igba mẹrin, ti meji jẹ ti CWC, Uefa Cup ati CL.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBode George: òòtọ́ ni ìkìlọ̀ Obasanjọ ati Soyinka

Kante ati Giroud pẹlu awọn agbabọọlu mọkanla lo kọkọ side ifẹsẹwọnsẹ fun ikọ Chelsea, nigba ti Aubameyang ati Lacazette yoo ma a gba fun Arsenal gẹgẹ bi agbabọọlu mọkanla akọkọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJiti Ogunye: Ìjọba àkóbá lológun gbé kalẹ̀ ni 1999