Àwòrán àwọn ìsẹ̀lẹ̀ lọ́ sẹ̀ yìí: ‘First Lady’ wọ asọ 1.6 milion Naira

Akojọpọ awọn aworan to lamilaaka:

Oloye Moshood Kashimawo Ọlawale Abiọla Image copyright @mko_abiola
Àkọlé àwòrán Ọjọbọ ọsẹ yii ni orilẹede Naijiria se Ayajọ Ọjọ ominira Naijiria lati fi da Oloye Moshood Kashimawo Ọlawale Abiọla lọla.
Aarẹ Muhammadu Buhari Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari re e ni ibi ayẹyẹ June 12 ni papa isere Eagle Square ni ilu Abuja to jẹ olu ilu orilẹede Naijiria.
Aisha Buhari Image copyright COPYRIGHT LUCIPOST
Àkọlé àwòrán Ibeere ti awọn ọmọ Naijiria n bere ni pe, ki ni iyawo aarẹ Buhari n se, ti o fi wọ asọ to fẹrẹ to miliọnu meji Naira?
June 12 Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aarẹ orilẹede mẹrin lo parapọ si papa isere Eagles Square lati ba Naijiria dse ayẹyẹ ọjọ ominira June 12
Ahmed Lawan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọsẹ yii bakan naa ni Sẹnatọ Ahmed Lawan di Aarẹ ile igbimọ Asofin Agba lorilẹede Naijiria lẹyin ti awọn asofin naa di ibo yan awọn adari tuntun.
Eko Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Bi o tilẹ jẹ pe ko ba ofin mu ki awọn eniyan ma a ta ọja ni ẹgbẹ ọna ni ipinlẹ Eko, awọn ọlọja nitori iya ati isẹ ma n tiraka lati duro si ẹgbẹ oju ọna lati ta ọja wọn.
Super Falcons Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ikọ Super Falcons naa fun Naijiria ni ẹbun ọjọ ominira lẹyin ti wọn naa ikọ South Korea ninu idije Women's World Cup to n lọ lọwọ lorilẹede Faranse
Thomas Dennerby Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Adari ikọ Super Falcons, Thomas Dennerby fi idunnu rẹ han lẹyin ti ikọ rẹ jawe olubori

Aworan yii wa lati ile isẹ Getty Images ati COPYRIGHT LUCIPOST