Insecurity: Agbẹkọya ní òògùn abẹnugọ̀ǹgọ̀ ní ọ̀nà àbáyọ fún ìjínigbé!

Comrade Abioye Akinbola Image copyright WIKIPEDIA
Àkọlé àwòrán Awọn Yoruba mọ ẹgbẹ Agbẹkọya gẹgẹ bi ẹgbẹ tó jẹ́ àgbà fun ẹgbẹ OPC tó ń jà fun ẹtọ́ awon ọmọ Yoruba.

Ẹgbẹ Agbẹkọya Peace Movement of Nigeria ti rọ ijọba lati lo ẹgbẹ awọn lati dẹkun eto aabo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria paapaa ni ilẹ Yoruba.

Adari ẹka ẹgbẹ Agbẹkọya Peace Movement ni ilu Abuja, Comrade Abioye Akinbola lo sọ eyi lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ọna abayọ si isekupani ati ijinigbe ni ilẹ Yoruba.

Comrade Abioye ni "idabobo Naijiria wa nilo ọgbọn inu ati ọgbọn ori, eleyi ti awọn agbaagba ẹgbẹ wa ni agbara ati ọgbọn inu bii oogun abẹnugọngọ ti wọn le lo lati dẹkun rẹ".

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi ni afunfèrè àkọ́kọ́ lágbo eré KWAM 1 ní 1983'

O ni pẹlu oogun abẹnugọngọ, awọn lee lo ọpa lai si ibọn tabi ọ̀kọ̀ lati dẹkun gbogbo ero inu awọn ajiinigbe. Wọn ni ti awọn ba ṣe eto silẹ tabi si awọn ilu ti iru awọn isẹlẹ yii ti n waye, wọn ko ni gburo rẹ mọ lailai.

Comrade Abioye fikun un wi pe ti ijọba ba pe ipade gbogboogbo, eleyii ti yoo se ijiroro pẹlu awọn adari ijọba ibilẹ ati awọn gomina pẹlu awọn ẹgbẹ bii Agbẹkọya ti yoo fun wọn ni ilana lati fopin si ijinigbe.

Adari ẹka ẹgbẹ Agbẹkọya Peace Movement naa to ni awọn ko lee da nkankan se lai si iranwọ ijọba, wa parọwa si ijọba lati pe ipade gbogboogbo ti awọn adari ijọba ibilẹ, gomina yoo kopa ninu rẹ, ti awọn yoo fi le lo ọgbọn inu awọn lati fi ran ijọba lọwọ.