NURTW: Agbẹnusọ Sanwo-Olu ní gómínà ti gbé ọ̀rọ̀ ìjà NURTW lé ọlọ́pàá lọ́wọ́

àwọn ọmọ ẹgbẹ awakọọ Naijiria n ṣe iwọde Image copyright Nurtw
Àkọlé àwòrán Sanwo-Olu kò lè tori ìjà Ojota fòfin de NURTW ní Eko

Ọrọ ija NURTW tijọba ipinlẹ Oyo ati Ogun ti fofin de lo n kọ àwọn eniyan lominu ni Eko.

Awuyewuye to waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ Ipinlẹ Eko ni iroyin ló ṣe iku pa ọkan lara wọn to gbẹmi mi ni ibudokọ Ọjọta.

Eyi lo mu ki BBC kan si ọọfiisi gomina Sanwo Olu lati mọ erongba wọn lati fopin si iṣẹlẹ yii ko too maa gbẹbọ lọwọ ipinlẹ Eko.

Agbẹnusọ Gomina Babajide Sanwo-Olu, Gboyega Akosile ṣalaye fun BBC Yoruba pé gomina naa ko gbero lati fofin de ẹgbẹ naa nilu Eko.

Ẹ ranti pe ipinlẹ Ogun ati Oyo fofin de ẹgbẹ naa nitori ipenija si ọrọ eto aabo ti ija laarin awọn ọmọ ẹgbẹ naa maa n fa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀyájọ́ òṣìṣẹ́: NURTW gba ẹ̀jẹ̀ lára àwọn òsìsẹ

Akosile, to jẹ igbakeji oluranlọwọ pataki fun gomina lori ọrọ iroyin sọ fun BBC Yoruba pe gomina Sanwo-Olu ti fa ọrọ naa le awọn ọlọpaa lọwọ lati ṣiṣẹ wọn,

O tun ṣalaye siwaju pe bi ọrọ NURTW ṣe ri ni awọn ipinlẹ ti awọn gomina ti fofin de ẹgbẹ naa yatọ si bo ṣe ri ni ipinlẹ Eko.

Ni ọdọọdun ni ija awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW maa n mu ẹmi dani ni Ipinlẹ Eko.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEkiti Election: Ẹgbẹ́ awakọ̀ Ekiti pa ìjọba dà lẹ́yìn tí wọ́n kéde Fayẹmi

Ni ọpọ igba ni iru ija bẹẹ maa n da lori ipo aṣaaju ninu ẹgbẹ naa.

Ni ọdun 2018, wahala bẹ silẹ ni Isalẹ Eko nigba ti wọn pa amugbalẹgbẹ ọkan lara awọn aṣaaju ẹgbẹ naa.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionafin pupa