Igba Marún-un ti Aisha Buhari ti tako ìjọba Buhari

Aisha Buhari Image copyright Aisha Buhari
Àkọlé àwòrán Aisha ni tí ènìyàn tó le ni mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dogún ba le dibo yan ọkọ òun wọle ti àwọn ènìyàn meji dondo si gba ìjọba láti keyin wọn si ààrẹ

Ìgba kan ń lọ ìgbà kán ń bọ ló ni ilé ayé.

Tọkọ taya ni wọn jọ ń wọ ile ìjọba ni Naijiria atawọn orilẹ-ede agbaye to pọ.

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ti a bá gbọ ohun àwọn obinrin wọ̀nyìí, ó ni láti jẹ pé lásìkò ti wọ́n ba n ṣe ètò ti ó jẹ ti wọ̀n ni.

Sùgbọ́n láti ọdun 2015 ti ààrẹ Muhammadu Buhari ti góri oyè gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ni aya rẹ̀, Aisha Buhari ti máa ń sọ òkò ọ̀rọ̀ ní ìgbàkúùgbà ti ààrẹ Buhari tàbi ẹgbẹ òṣèlú APC bá ti tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀.

Ìgbà mẹ́rin ti Aisha Buhari ti sọ̀rọ̀ lòdi si ìjọ APC

"Ìgbìmọ ẹlẹ́ni méji ló ń dari ọkọ mi"

Ní ibi ìpàdé àpérò kan nilu Abuja ní Aisha ti pe awọn ọmọ Naijíríà nija láti kọju ìjà si àwọn ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni méji si mẹ́ta tó n dari ìjọba Muhammadu Buhari lòdì si àwọn ènìyàn Nàìjíríà.

Aisha ni kò dara to pe kí ènìyàn tó le ni mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dogún dibo yan ọkọ òun wọle ti àwọn ènìyàn meji dondo si gba ìjọba láti keyin awọn naa si ààrẹ.

O pe àwọn okunrin Nàìjíríà nija láti dide ki wọ́n ba wọn ja.

Sááju àsìkò yìí ni Aisha Buhari ti ba BBC Hausa sọ̀rọ̀ lọdun 2016 pe àwọn kan lo ń dari ọkọ òun nilé ìjọba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSogidi Lake: Kòṣẹja-kòṣèèyàn lá bá nínú adágún odò náà -Ojedele

"Bí ẹgbẹ́ òsèlú APC ṣe ń seto ìdìbò Abẹ́lé kò tó rárá"

Lárá ǹkan ti o tún dá awuyewuye sílẹ̀ ní bi aya ààrẹ ṣe kọlu alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC Adams Oshiomhole.

Aisha ni ìwà àìtọ ló n hù nínú ẹgbẹ́ pàápàá julọ lóri ètò ẹgbẹ́.

O ni alága ẹgbẹ́ ń farun iwaju pọ̀ mọ ti ìpàkọ́ fún gbogbo àwọn ọmọ égbẹ́, èyí sì ló ń dá yánpón-yanrin silẹ̀ ninu ẹgbẹ́ APC.

Ọ̀rọ̀ yìí jẹyọ nígbà ti àbúrò aya ààrẹ gbégbà ìbò ìdìbò abẹ́lé fún ìpò Gomina ni ìpínlẹ̀ Adamawa sùgbọ́n ti kò wọle.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFlorida: Ọ̀ọ̀nì àléègbà dé ba Mary lálejò lọ́gànjọ́ òru

"Ó ṣeéṣe ki n ma ti ọkọ mi lẹ́yìn nínú ìdìbò tó n bọ"

Ṣáájú ìdìbò ọdun 2019 ní aya ààrẹ orilẹ̀-èdè Naijíríà sọ pé ó ṣeese láti má fọ̀wọ̀sowọpọ lóri ìdìbò 2019.

Aisha Buhari sọ èyí di mímọ̀ lásiko tó ń ba BBC sọ̀rọ̀, ó ni ọ̀pọ̀ àwọn mínísítà tó n ba ọ̀kọ òun ṣiṣẹ́ ni kò damọ.

Ó fi kùn un pé onírúuru awuyewuye ni òun ti n gbọ ti eti òun sì ti kún lóri ọ̀rọ náà.

Ọ̀rọ̀ yìí dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ aríyanjiyan sílẹ̀ lórí ẹ̀rọ twitter

Àkọlé àwòrán Aisha ni tí ènìyàn tó le ni mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dogún ba le dibo yan ọkọ òun wọle ti àwọn ènìyàn meji dondo si gba ìjọba láti keyin wọn si ààrẹ

"Àwọn obinrin Kano kò jànfàní owó amúlúdùn fún àwọn toosi jùlọ"

Láìpẹ yìí ni ìyàwó ààrẹ tún bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lú èto ìjọba Muhammadu Buhari lóri pínpín owó ẹdẹ́gbẹ̀ta bílíọ̀nú náírà tó wà fún àwọn tó tòsì jùlọ pàápàá jùlọ ni ìhà Arewa.

Èyí jẹ alébu sí ìjọba ààrẹ Muhammadu Buhari ti ọ̀pọ̀ àwọ̀n eníyan bẹ̀rẹ̀ si ni gbàá bí ẹni gab igba oti.

"Miò faramọ́ ìyànsípò Festus Adedayo"

Lánàá òde yìí ni Aisha tún fi ohun rẹ̀ síta lóri ìyànsípò agbẹ́nusọ fún ààrẹ ilé ìgbìmọ aṣòfin agbà Ahmed Lawan tó fẹ yan Festus Adedayo sípò.

Gẹ́gẹ́ bi ìṣe rẹ̀ aya ààrẹ gbá ojú òpó twitter rẹ̀ lọ láti pa òhun pọ pẹ̀lú àwan ọmọ égbẹ òṣèlú APC tó kù láti tako Festus Adedayo pé kò ṣesṣe ki ènìyàn maa tèlé ìjọba ti kò ni ìgbàgbọ ninu rẹ̀.

Eyi lo ti bi eso ti aarẹ ile igbimọ aṣofin ti fi yọ Festus Adedayọ nipoKò dùn mí pé mo sọ̀rọ̀ tako Buhari -Adedayo Festus